Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 18:4-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ó yẹ kí wọ́n darapọ̀ mọ́ ọ láti jẹ ìyà iṣẹ́ fún àìtọ́jú ibi ti Àgọ́ Ìpàdé àti gbogbo iṣẹ́ tí ó wà ní ibi àgọ́, àti wí pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó le wá sí ẹ̀gbẹ́ ibi tí o wà.

5. “Kí o sì mójú tó iṣẹ́ ibi mímọ́ àti iṣẹ́ ibi pẹpẹ, kí ìbínú má ba wá sí orí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́.

6. Èmi fúnra mi ti yan àwọn arákùnrin rẹ tí í ṣe ọmọ Léfì kún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóòkù, wọn jẹ́ ẹ̀bùn fún ọ, èyí ni a fún Olúwa láti ṣe iṣẹ́ tí ó wà ní àgọ́ ìpàdé.

7. Ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ni yóò mójú tó iṣẹ́ àlùfáà yín fún gbogbo ohun tó bá jẹ mọ́ ibi pẹpẹ àti ti ẹ̀yin aṣọ títa, ẹ ó sì máa ṣiṣẹ́ ibi pẹpẹ àti nínú aṣọ tí a ta. Mo fún ọ ní iṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn. Ṣùgbọ́n àlejò tí ó bá sún mọ́ tòòsí ibi ìyà sí mímọ́ fún Ọlọ́run ni a ó pa.”

8. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Árónì pé, “Èmi fúnra mi ti fi ọ́ ṣọ́ ìdi gbogbo ẹbọ tí a bá mú wá fún gbogbo ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá fún mi, mo fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpín rẹ tí yóò máa ṣe.

9. Ìwọ ni kí o ni ìpín ọrẹ mímọ́ jùlọ tí a mú kúrò ní ibi iná, nínú gbogbo ọrẹ tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ mímọ́ jùlọ, yálà ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ẹbọ ẹ̀bi, ìpin wọ̀nyí jẹ́ ti ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ.

10. Ẹ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ jùlọ, gbogbo ọkùnrin ni ó gbọdọ̀ jẹ ẹ́. Ó gbọdọ̀ kà á sí mímọ́,

11. “Èyí tún jẹ́ tìrẹ pẹ̀lú: ohunkóhun tí a bá yà sọ́tọ̀ lára ẹ̀bùn ọrẹ fífì àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Mó fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ipin tí yóò máa ṣe déédé nínú ìdílé rẹ, tí o bá wà ní mímọ́ ni o le jẹ ẹ́.

12. “Mo fún ọ ní gbogbo òróró tí ó dára jùlọ àti gbogbo ọtí titun dáradára jùlọ àti ọkà tí wọ́n mú wá fún Olúwa ní àkọ́so ohun ọ̀gbìn wọn tí wọ́n kórè.

13. Gbogbo àkọ́so nǹkan ilẹ̀ wọ́n tí wọn mú wá fún Olúwa yóò jẹ́ tìrẹ, Ẹnikẹ́ni nínú ìdílé rẹ, àwọn tí ó jẹ́ mímọ́ nínú ìdílé rẹ lè jẹ ẹ́.

14. “Gbogbo nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa ní Ísírẹ́lì jẹ́ tìrẹ.

15. Gbogbo àkọ́bí nínú gbogbo ohun alààyè tí wọ́n mú wá fún Olúwa, ìbá à jẹ́ ti ènìyàn tàbí ti ẹranko jẹ́ tìrẹ ṣùgbọ́n o gbọdọ̀ ra gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin padà àti àkọ́bí àwọn ẹranko aláìmọ́.

16. Nígbà tí wọ́n bá pé oṣù kan, o gbọdọ̀ rà wọ́n padà ní iye owó ìràpadà tí í ṣe ṣékélì márùn ún fàdákà, gẹ́gẹ́ bí iye ṣékélì ibi mímọ́ tí ó wọn ìwọn ogún (20) gérà.

17. “Ṣùgbọ́n o kò gbọdọ̀ ra àwọn àkọ́bí ọmọ màlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́; wọ́n jẹ́ mímọ́. Wọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn sórí pẹpẹ kí o sì sun ọ̀rá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àfinásun, ẹbọ òórùn dídùn sí Olúwa.

18. Ẹran wọn gbọdọ̀ jẹ́ tìrẹ, gẹ́gẹ́ bí ìgẹ̀ ọrẹ ẹbọ fífì àti itan ọ̀tún ṣe jẹ́ tìrẹ.

19. Ohunkóhun tí a bá ti yà sọ́tọ̀ nínú ọrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n mú wá fún Olúwa ni mo fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìpín rẹ tí yóò máa ṣe déédé. Ó jẹ́ májẹ̀mú iyọ̀ láéláé níwájú Olúwa fún ìwọ àti ọmọ rẹ.”

20. Olúwa sọ fún Árónì pé, “O kò ní ní ogún nínú ilẹ̀ wọn bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ní ní ìpín láàrin wọn, Èmi ni ìpín àti ogún rẹ láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

21. “Mó ti fún àwọn ọmọ Léfì ní gbogbo ìdámẹ́wàá ní Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ogún fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe, nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ níbi àgọ́ ìpàdé

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 18