Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 14:6-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Jóṣúà ọmọ Núnì àti Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè, tí wọ́n wà lára àwọn to lọ yẹ ilẹ̀ wò sì fa aṣọ wọn ya.

7. Wọ́n sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì pé, “Ìlẹ̀ tí a là kọjá láti yẹ̀ wò náà jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.

8. Bí inú Olúwa bá dùn sí wa, yóò mú wa dé ilẹ̀ náà, ilẹ̀ tó ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin, yóò fún wa ní ilẹ̀ náà.

9. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ̀tẹ̀ sí Olúwa. Kí ẹ sì má bẹ̀rù àwọn ènìyàn ìlú náà, nítorí pé a ó gbé wọn mì, ààbò wọn ti fi wọ́n sílẹ̀, Olúwa sì wà pẹ̀lú àwa, Ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn.”

10. Ṣùgbọ́n gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń sọ pé àwọn yóò sọ wọ́n lókúta pa. Nígbà náà ni ògo Olúwa fara hàn ní Àgọ́ Ìpàdé níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

11. Olúwa sọ fún Mósè pé: “Fún ìgbà wo ni àwọn ènìyàn yìí yóò ti kẹ́gàn mi tó? Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí wọ́n ó fi kọ̀ jálẹ̀ láti gbà mí gbọ́, pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ àmì tí mo ṣe láàrin wọn?

12. Èmi ó kọlù wọ́n pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn, èmi ó gba ogún wọn lọ́wọ́ wọn, èmi ó sì pa wọ́n run ṣùgbọ́n èmi ó sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá tó sì lágbára jù wọ́n lọ.”

13. Ṣùgbọ́n Mósè sọ fún Olúwa pé, “Nígbà náà ni àwọn ará Éjíbítì yóò gbọ́; Nítorí pé nípa agbára Írẹ ni ìwọ fi mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí jáde kúrò láàrin wọn.

14. Wọ́n ó sì sọ fún àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí. Àwọn tó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ìwọ Olúwa wà láàrin àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti pé wọ́n rí ìwọ, Olúwa, ní ojúkojú, àti pé ìkùukùu àwọsánmọ̀ rẹ dúró lórí wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì ń lọ níwájú wọn pẹ̀lú ìkùukùu àwọsánmọ̀ ní ọ̀sán àti pẹ̀lú ọ̀wọ́n iná ní òru.

15. Bí ìwọ bá pa àwọn ènìyàn wọ̀nyí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, àwọn orílẹ̀ èdè tó bá gbọ́ ìròyìn yìí nípa rẹ yóò wí pé.

16. ‘Nítorí pé Olúwa kò le è mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí dé ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún wọn; torí èyí ló ṣe pa wọ́n sínú ihà yìí.’

17. “Báyìí, mo gbàdúrà, jẹ́ kí agbára Olúwa tóbi gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣọ pé:

18. ‘Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ tó dúró sinsin, tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá jìn. Bẹ́ẹ̀ ni kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà; tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹta àti ìran kẹrin.’

19. Dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn yìí jìn wọ́n, mo bẹ̀ ọ́, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ńlá rẹ, bí o ti ṣe ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jìn wọ́n láti ìgbà tí o ti kó wọn kúrò ní Éjíbítì di ìsin yìí.”

20. Olúwa sì dáhùn pé: “Mo ti dárí jìn wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ;

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 14