Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Náhúmù 3:4-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn panṣágààgbèrè tí ó rójú rere gbà,Iyá àjẹ́ tí ó sọ́ àwọn orilẹ̀-èdè di ẹrúnipa àgbèrè rẹ̀àti àwọn ìdílé nipa ìṣe àjẹ́ rẹ̀.

5. “Èmi dojú kọ ọ́,” ni Olúwa awọn ọmọ ogun wí.“Èmi ó si ká aṣọ ìtẹ́lẹ̀dì rẹ ní ojú rẹ,Èmi yóò sì fi ìhòòhò rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdèàti ìtìjú rẹ̀ han àwọn ilẹ̀ ọba.

6. Èmi yóò da ẹ̀gbin tí ó ni ìríra sí ọ ní ara,èmi yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà.

7. Kò sí ṣe pé, gbogbo àwọn tí ó ba sì wò ọ́ yóò sì káàánú fún ọ, wọn yóò sì wí pé,‘Nínéfè ṣòfò: Ta ni yóò kẹ́dùn rẹ?’Níbo ni èmi o ti wá olùtùnú fún ọ?”

8. Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn ju Tébésì lọ,èyí tí ó wà ní ibi odò, Náílìtí omi sì yí káàkiri?Odò náà sì jẹ́ ààbò rẹ̀,omi si jẹ́ odi rẹ̀.

9. Etiópíà àti Éjíbítì ni agbára rẹ, kò sí ní òpin;Pútì àti Líbíà ni àwọn olùgbèjà rẹ̀.

10. Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ a kó o ní ìgbèkùno sì lọ sí oko ẹrú.Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ̀ ni a ó fọ́ mọ́lẹ̀ní orí ìta gbogbo ìgboro.Wọ́n sì di ìbò nítorí àwọn ọlọ́lá rẹ̀ ọkùnrin,gbogbo àwọn ọlọ́lá rẹ ni a sì fi ẹ̀wọ̀n dè

11. Ìwọ pẹ̀lú yóò sì mu àmupara;a ó si fi ọ́ pamọ́ìwọ pẹ̀lú yóò máa ṣe àfẹ́rí ààbò nítorí ti ọ̀tá náà.

12. Gbogbo ilé-ìṣọ́ agbára rẹ yóò dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́pẹ̀lú àkọ́pọ́n èso wọn;Nígbà tí wọ́n bá ń gbọ̀n wọ́n,ọ̀pọ̀tọ́ yóò sì bọ́ sí ẹnu àwọn ọ̀jẹun.

13. Kíyè sí,Obínrin ni àwọn ènìyàn rẹ ní àárin!Ojú ibodè rẹ ní a ó sí sílẹ̀ gbagada,fún àwọn ọ̀tá rẹ̀;iná yóò jó ilẹ̀ rẹ

Ka pipe ipin Náhúmù 3