Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 8:8-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Nígbà tí ẹ bá ti gba ìlú náà, kí ẹ sì ti iná bọ̀ ọ́. Kí ẹ ṣe ohun tí Olúwa pàṣẹ. Mo ti fi àṣẹ fún un yín ná.”

9. Nígbà náà ni Jóṣúà rán wọn lọ. Wọ́n sì lọ sí ibùba, wọ́n sì sùn ní àárin Bétélì àti Áì, ní ìwọ̀-oòrùn Áì. Ṣùgbọ́n Jóṣúà wá dúró pẹ̀lú àwọn ènìyan ní orú ọjọ náà.

10. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kéjì Jóṣúà kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀, òun àti àwọn olórí Ísírẹ́lì, wọ́n wọ́de ogun lọ sí Áì.

11. Gbogbo àwọn ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú u rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì súnmọ́ tòsí ìlú náà, wọ́n sì dé iwájú u rẹ̀. Wọ́n sì pàgọ́ ní ìhà àríwá Áì. Àfonífojì sì wà ní agbede-méjì wọn àti ìlú náà.

12. Jóṣúà sì ti fi bí ẹgbẹ̀rún márùn ún ọmọ ogun pamọ́ sí àárin Bétélì àti Áì, sí ìwọ̀-òòrùn ìlú náà.

13. Wọ́n sì yan àwọn ọmọ ogun sí ipò wọn, gbogbo àwọn tí ó wà ní ibùdó lọ sí àríwá ìlú náà àti àwọn tí ó ṣápamọ́ sí ìwọ̀-òrùn rẹ̀. Ní òru ọjọ́ náà Jóṣúà lọ sí àfonífojì.

14. Nígbà tí ọba Áì rí èyí, òun àti gbogbo ọkùnrin ìlú náà yára jáde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù láti pàdé ogun Ísírẹ́lì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aginjù. Ṣùgbọ́n kò mọ̀ pé àwọn kan wà ní ibùba ní ẹ̀yìn ìlú náà.

15. Jóṣúà àti gbogbo àwọn Ísírẹ́lì sì ṣe bí ẹni tí a lé padà níwájú wọn, wọ́n sì ṣá gba ọ̀nà ihà.

16. A sì pe gbogbo àwọn ọkùnrin Áì jọ láti lépa wọn, wọ́n sì lépa Jóṣúa títí wọ́n fi tàn wọ́n jáde nínú ìlú náà.

17. Kò sì ku ọkùnrin kan ní Áì tàbi Bétélì tí kò tẹ̀lé Ísírẹ́lì. Wọ́n sì fi ìlẹ̀kùn ibodè náà sílẹ̀ ní ṣíṣí, wọ́n sì ń lépa àwọn ará Ísírẹ́lì.

18. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Jóṣuà pé, “Na ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ ọ rẹ sí Áì, nítorí tí èmi yóò fi ìlú náà lé ọ ní ọwọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà sì na ọ̀kọ̀ ọwọ́ ọ rẹ̀ sí Áì.

19. Bí ó ti ṣe èyí tán, àwọn ọkùnrin tí ó ba sì dìde kánkán kúrò ní ipò wọn, wọ́n sáré ṣíwájú. Wọn wọ ìlú náà, wọ́n gbà á, wọ́n sì yára ti iná bọ̀ ọ́.

20. Àwọn ọkùnrin Áì bojú wo ẹ̀yìn, wọ́n rí èéfín ìlú náà ń gòkè lọ sí ọ̀run, ṣùgbọ́n wọn kò rí, àyè láti sá àsálà lọ sí ibìkan kan, nítorí tí àwọn ará Ísírẹ́lì tí wọ́n tí ń sálọ sí ihà ti yípadà sí àwọn tí ń lépa wọn.

21. Nígbà tí Jóṣúà àti gbogbo àwọn ará Ísírẹ́lì rí i pé àwọn tí ó ba ti gba ìlú náà, tí èéfín ìlú náà sì ń gòkè, wọ́n yí padà wọ́n sì kọlu àwọn ọkùnrin Áì.

Ka pipe ipin Jóṣúà 8