Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 7:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ṣùgbọ́n àwọn ará Ísírẹ́lì ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàṣọ́tọ̀, Ákánì ọmọ Kámì, ọmọ Símírì, ọmọ Ṣérà, ẹ̀yà Júdà, mú nínú wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Olúwa ru sí àwọn ará Ísírẹ́lì.

2. Jóṣúà rán àwọn ọkùnrin láti Jẹ́ríkò lọ sí Áì, tí ó sún mọ́ Bẹti-Áfẹ́nì ní ìlà-oòrùn Bétélì, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gòkè lọ kí ẹ sì ṣe amí.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn arákùnrin náà lọ, wọ́n sì yọ́ Áì wò.

3. Nígbà tí wọ́n padà sí ọ̀dọ̀ Jósúà, wọ́n wí pé, “Kì í ṣe gbogbo àwọn ènìyàn ni ó ni láti gòkè lọ bá Áì jà. Rán ẹgbẹ̀rún méjì tàbí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkùnrin láti gbà á, kí ó má ṣe dá gbogbo àwọn ènìyàn ní agara, nítorí ìba ọkùnrin díẹ̀ ní ó wà níbẹ̀.”

4. Bẹ́ẹ̀ ní àwọn bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkùnrin lọ; ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Áì lé wọn sá,

5. wọ́n sì pa àwọn bí mẹ́rìndínlógójì nínú wọn. Wọ́n sì ń lépa àwọn ará Ísírẹ́lì láti ibodè ìlú títí dé Ṣébárímù, wọ́n sì pa àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀. Àyà àwọn ènìyàn náà sì já, ọkàn wọn sì pámi.

6. Jósúà sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dojú bolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa títí di àṣálẹ́. Àwọn àgbà Ísírẹ́lì sì ṣe bákan náà, wọ́n ku eruku sí orí i wọn.

7. Jósúà sì wí pé, “Háà, Olúwa Ọlọ́run alágbára, nítorí i kiín ni ìwọ ṣe mú àwọn ènìyàn yìí kọjá a Jọ́dánì, láti fi wọ́n lé àwọn ará Ámórì lọ́wọ́; láti pa wọn run? Àwa ìbá mọ̀ kí a dúró ní òdì kéjì Jọ́dánì?

8. Olúwa, kín ni èmi yóò sọ nísinsin yìí tí Ísírẹ́lì sì ti sá níwájú ọ̀ta a rẹ̀.?

9. Àwọn Kénánì àti àwọn ènìyàn ìlú tí ó kù náà yóò gbọ́ èyí, wọn yóò sì yí wa ká, wọn yóò sì ké orúkọ wa kúrò ní ayé. Kí ni ìwọ ó ha ṣe fún orúkọ ńlá à rẹ?”

10. Olúwa sì sọ fún Jóṣúà pé, “Dìde! Kín ni ìwọ ń ṣe tí ó fi dojú bolẹ̀?

11. Ísírẹ́lì ti ṣẹ̀; Wọ́n sì ti ba májẹ̀mú mi jẹ́, èyí tí mo pàṣẹ fún wọn pé kí wọn pamọ́. Wọ́n ti mú nínú ohun ìyàsọ́tọ̀, wọ́n ti jí, wọ́n pa irọ́, Wọ́n ti fi wọ́n sí ara ohun ìní wọn.

12. Ìdí nì-yí tí àwọn ará Ísírẹ́lì kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀ta wọn; wọ́n yí ẹ̀yín wọn padà, wọ́n sì sálọ níwájú ọ̀ta a wọn nítorí pé àwọn gan-an ti di ẹni ìparun. Èmi kì yóò wà pẹ̀lú u yín mọ́, bí kò se pé ẹ̀yin pa ohun ìyàṣọ́tọ̀ run kúrò ní àárin yín.

13. “Lọ, ya àwọn ènìyàn náà sí mímọ́. Sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ fún ọ̀la, nítorí báyìí ni Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Ohun ìyàsọ́tọ̀ kan ń bẹ ní àárin yín, Ìwọ Ísírẹ́lì. Ẹ̀yin kì yóò lè dúró níwájú àwọn ọ̀ta a yín títí ẹ̀yin yóò fi mú kúrò.

14. “ ‘Ní òwúrọ̀ kí ẹ mú ará yín wá ṣíwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀yà tí Olúwa bá mú yóò wá sí iwájú ní agbo ilé kọ̀ọ̀kan, agbo ilé tí Olúwa bá mú yóò wá sí iwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, ìdílé tí Olúwa bá sì mú yóò wá sí iwájú ní ẹni kọ̀ọ̀kan.

15. Ẹnikẹ́ni tí a bá ká mọ́ pẹ̀lú ohun ìyàṣọ́tọ̀ náà, a ó fi iná paárun, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní. Ó ti ba májẹ̀mú Olúwa jẹ́, ó sì ti ṣe nǹkan ìtìjú ní Ísírẹ́lì!’ ”

16. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kéjì, Jóṣúà mú Ísírẹ́lì wá ṣíwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, a sì mú ẹ̀yà Júdà.

17. Àwọn agbo ilé e Júdà wá sí iwájú, ó sì mú agbo ilé Sérátì. Ó sì mú agbo ilé Sérátì wá ṣíwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, a sì mú ìdílé Símírì.

18. Jóṣúà sì mú ìdílé Símírì wá ṣíwájú ní ọkùnrin kọ̀ọ̀kan, a sì mú Ákánì ọmọ Kámì, ọmọ Símírì, ọmọ Sérà ti ẹ̀yà Júdà.

Ka pipe ipin Jóṣúà 7