Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóẹ́lì 2:8-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò to ẹnìkejì rẹ̀;olúkúlukù wọn yóò rìn ní ọ̀nà rẹ̀:nígbà tí wọn bá sì ṣubú lù ìdàwọn kì yóò gbọgbẹ́.

9. Wọn yóò sáré síwá ṣẹ́yìn ní ìlú;wọn yóò súré lórí odi,wọn yóò gùn orí ilé;wọn yóò gbà ojú fèrèsé wọ̀ inú ilé bí olè.

10. Ayé yóò mì níwájú wọn;àwọn ọ̀run yóò wárìrì;òòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn,àwọn ìràwọ̀ yóò sì fà ìmọ́lẹ̀ wọn ṣẹ́yìn.

11. Olúwa yóò sì bú rámu ramùjáde níwájú ogun rẹ̀:nítorí ibùdó rẹ̀ tóbi gidigidi;nítorí alágbára ní òun, tí n mú ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ;nítorí ọjọ́ Olúwa tóbi ó sì ní ẹ̀rù gidigidi;ara ta ni ó lè gbà á?

12. “Njẹ́ nítorí náà nísínsin yìí,” ni Olúwa wí,“Ẹ fi gbogbo ọkàn yín yípadà sí mi,àti pẹ̀lú ààwẹ̀, àti pẹ̀lú ẹkún, àti pẹ̀lú ọ̀fọ̀.”

13. Ẹ sì fa ọkàn yín ya,kì í sì í ṣe aṣọ yín,ẹ sì yípadà sí Olúwa Ọlọ́run yín,nítorí tí o pọ̀ ní oore ọ̀fẹ́,ó sì kún fun àánú, ó lọ́ra láti bínú,ó sì ṣeun púpọ̀, ó sì ronúpìwàdà láti ṣe búburú.

14. Ta ni ó mọ̀ bí òun yóò yípadà,kí o sì ronúpìwàdà,kí ó sì fí ìbùkún sílẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀;àní ọrẹ jíjẹ àti ọrẹ mímu fún Olúwa Ọlọ́run yín?

15. Ẹ fún ìpè ní Ṣíónì,ẹ ya ààwẹ̀ kan sí mímọ́,ẹ pe àjọ tí ó ni ìrònú.

16. Ẹ kó àwọn ènìyàn jọ,ẹ ya ìjọ sí mímọ́;ẹ pe àwọn àgbà jọ,ẹ kó àwọn ọmọdé jọ,àti àwọn tí mú ọmú:jẹ kí ọkọ ìyàwó kúrò nínú iyẹ̀wù rẹ̀.Kí ìyàwó sì kúrò nínù ìyàrá rẹ̀

17. Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ Olúwa,sọkún láàrin ìlorò àti pẹpẹ,sí jẹ́ kí wọn wí pé, “Dá àwọnènìyàn rẹ sí Olúwa,má sì ṣe fi ìní rẹ fun ẹ̀gàn,ti àwọn aláìkọlà yóò fi má jọba lórí wọn:èéṣe tí wọn yóò fi wí láàárin àwọn ènìyàn pé,‘Ọlọ́run wọn há da?’ ”

Ka pipe ipin Jóẹ́lì 2