Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóẹ́lì 2:20-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. “Ṣùgbọ́n èmi yóò lé ogun àríwá jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ yín,èmi yóò sì lé e lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣá, tí ó sì di ahoro,pẹ̀lú ojú rẹ̀ sí òkun ìlà oòrùn,àti ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìwọ̀ oòrùn òkun.Oòrùn rẹ̀ yóò sì gòkè,òórùn búburú rẹ̀ yóò sì gòkè.”Nítòótọ́ ó ti ṣe ohun ńlá.

21. Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀;jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn kí o sì yọ̀,nítorí Olúwa ti ṣe ohun ńlá,

22. Ẹ má bẹ̀rù, ẹranko igbó,nítorí pápá-oko ihà ń rú,nítorí igi ń so èso rẹ̀, igi ọ̀pọ̀tọ́àti àjàrà ń so èso ipá wọn.

23. Ǹjẹ́ jẹ́ kí inú yín dùn, ẹ̀yin ọmọ Ṣíónì,ẹ sì yọ̀ nínú Olúwa Ọlọ́run yín,nítorí ó ti fi àkọ́rọ̀ òjò fún yín bí ó ti tọ́,Òun ti mú kí òjò rọ̀ sílẹ̀ fún un yín,àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní oṣù kìn-ín-ní.

24. Àwọn ilẹ̀ ìpàkà yóò kún fún ọkà;àti ọpọ́n wọn nì yóò ṣàn jádepẹ̀lú ọti wáìnì tuntun àti òróró.

25. “Èmi yóò sì mú ọdún wọ̀nyí ti eṣú jẹ run padà fún un yín.Èyí tí eṣú agénijẹ àti eṣú jewéjewéọwọ́ eṣú agénijẹ àti kòkòro ajẹnirun mìíràn ti fi jẹàwọn ogun ńlá mí tí mo rán sí àárin yín.

26. Ẹ̀yin yóò ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti jẹ, titi ẹyin yóò fi yóẹ ó sì yín orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín,ẹni tí ó fi ìyanu bá yín lò;ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mi láéláé.

27. Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, èmi wà láàrin Ísírẹ́lì,àti pé; Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín,ati pé kò sí ẹlòmíràn:ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mí láéláé.

28. “Yóò sì ṣe,èmi yóò tú ẹ̀mi mí sí ara ènìyàn gbogbo;àti àwọn ọmọ yín ọkùnrin,àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa ṣọtẹ́lẹ̀,àwọn arúgbó yín yóò máa lá àlá,àwọn ọ̀dọ́mọ́kunrìn yín yóò máa ríran.

29. Àti pẹ̀lú sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ọkùnrin,àti sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin,ní èmi yóò tú ẹ̀mi mí jáde ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì.

30. Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn ní ọrunàti ní àyé,ẹ̀jẹ̀ àti iná, àti ọ̀wọ́n èéfín.

31. A á sọ oòrùn di òkùnkùn,àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀,kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ẹ̀ru Olúwa tó dé.

32. Yóò sí ṣe ẹnikẹ́ni tí ó ba ké pèorúkọ Olúwa ní a ó gbàlà:nítorí ní òkè Ṣíónì àti ní Jérúsálẹ́mùní ìgbàlà yóò gbé wà,bí Olúwa ti wí,àti nínú àwọnìyókù tí Olúwa yóò pè.

Ka pipe ipin Jóẹ́lì 2