Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóẹ́lì 2:13-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ẹ sì fa ọkàn yín ya,kì í sì í ṣe aṣọ yín,ẹ sì yípadà sí Olúwa Ọlọ́run yín,nítorí tí o pọ̀ ní oore ọ̀fẹ́,ó sì kún fun àánú, ó lọ́ra láti bínú,ó sì ṣeun púpọ̀, ó sì ronúpìwàdà láti ṣe búburú.

14. Ta ni ó mọ̀ bí òun yóò yípadà,kí o sì ronúpìwàdà,kí ó sì fí ìbùkún sílẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀;àní ọrẹ jíjẹ àti ọrẹ mímu fún Olúwa Ọlọ́run yín?

15. Ẹ fún ìpè ní Ṣíónì,ẹ ya ààwẹ̀ kan sí mímọ́,ẹ pe àjọ tí ó ni ìrònú.

16. Ẹ kó àwọn ènìyàn jọ,ẹ ya ìjọ sí mímọ́;ẹ pe àwọn àgbà jọ,ẹ kó àwọn ọmọdé jọ,àti àwọn tí mú ọmú:jẹ kí ọkọ ìyàwó kúrò nínú iyẹ̀wù rẹ̀.Kí ìyàwó sì kúrò nínù ìyàrá rẹ̀

17. Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ Olúwa,sọkún láàrin ìlorò àti pẹpẹ,sí jẹ́ kí wọn wí pé, “Dá àwọnènìyàn rẹ sí Olúwa,má sì ṣe fi ìní rẹ fun ẹ̀gàn,ti àwọn aláìkọlà yóò fi má jọba lórí wọn:èéṣe tí wọn yóò fi wí láàárin àwọn ènìyàn pé,‘Ọlọ́run wọn há da?’ ”

18. Nígbà náà ní Olúwa yóò jowú fún ilẹ̀ rẹ̀,yóò sì káànú fún ènìyàn rẹ̀.

19. Nítòótọ́, Olúwa yóò dá wọn lóhùn:“Yóò sì wí fun àwọn ènìyàn rẹ̀ pé,Wò ó èmi yóò rán ọkà, àti ọtí wáìnì tuntun,àti òróró síi yín, a ó sì fi wọn tẹ́ yín lọ́rùn:èmi kì yóò si fí yín ṣe ẹ̀gan mọ́ láàrin àwọn aláìkọlà.

20. “Ṣùgbọ́n èmi yóò lé ogun àríwá jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ yín,èmi yóò sì lé e lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣá, tí ó sì di ahoro,pẹ̀lú ojú rẹ̀ sí òkun ìlà oòrùn,àti ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìwọ̀ oòrùn òkun.Oòrùn rẹ̀ yóò sì gòkè,òórùn búburú rẹ̀ yóò sì gòkè.”Nítòótọ́ ó ti ṣe ohun ńlá.

21. Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀;jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn kí o sì yọ̀,nítorí Olúwa ti ṣe ohun ńlá,

Ka pipe ipin Jóẹ́lì 2