Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 9:5-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ọ̀rẹ́ ń dalẹ̀ ọ̀rẹ́. Kò sì sí ẹnitó sọ òótọ́, wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọnláti máa purọ́. Wọ́n sọ ara wọndi onírẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀

6. Ó ń gbé ní àárin ẹ̀tànwọ́n kọ̀ láti mọ̀ mí nínúẹ̀tàn wọn,ni Olúwa wí.

7. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí:“Wò ó, èmi dán wọn wo; nítorí pékí ni èmi tún le è ṣe? Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi?

8. Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóróó ń sọ ẹ̀tàn; oníkálukú sì ńfi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà síaládúgbò rẹ̀; ní inúọkàn rẹ̀, ó dẹ tàkúté sílẹ̀.

9. Èmi kì yóò háa fi ìyà jẹ wọ́n nítorí èyí?”ni Olúwa wí.“Èmi kì yóò ha gbẹ̀san arami lórí irú orílẹ̀ èdè yìí bí?”

10. Èmi yóò sì sunkún, pohùnréréẹkún fún àwọn òkè; àti ẹkúnìrora lórí pápá oko ihà wọ̀n-ọn-nì.Nítorí wọ́n di ahoro, wọn kò sìkọjá ní ibẹ̀. A kò sì gbọ́ igbeẹran ọ̀sìn, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀runsì ti sá lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹranko sì ti lọ.

11. “Èmi yóò sì sọ Jérúsálẹ́mù di òkìtìàlàpà àti ìhò àwọn ìkokò.Èmi ó sì sọ ìlú Júdà di ahorotí ẹníkẹ́ní kò sì ní le è gbé.”

12. Ta ni ẹni náà tí ó ní ọgbọ́n láti mòye nǹkan wọ̀nyí? Ta ni Olúwa ti sọ èyí fún, tí ó sì lè ṣàlàyé rẹ̀? È é ṣe tí ilẹ̀ náà fi ṣègbé bí ihà, tí ẹnìkankan kò sì le là á kọjá?

13. Olúwa sì wí pé, nítorí pé wọ́n ti kọ òfin mi sílẹ̀, èyí tí mo gbé kalẹ̀ níwájú wọn, wọn ṣe àìgbọ́ràn sí wọn, wọn kò sì rìn nínú òfin mi.

14. Dípò èyí, wọ́n ti tẹ̀lé agídí ọkàn wọn, wọ́n ti tẹ̀lé Báálì gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe kọ́ wọn.

15. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, “Wò ó, Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ oúnjẹ kíkorò àti láti mu omi májèlé.

16. Èmi yóò sì tú wọn ká láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, nínú èyí tí àwọn tàbí àwọn baba wọn kò mọ̀. Èmi yóò sì lépa wọn pẹ̀lú idà títí èmi yóò fi pa wọ́n run.”

17. Èyí sì ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí:“Ṣáà wò ó nísisìnyìí! Ké sí obìnrin ọlọ́fà nì kí ó wá;sì ránsẹ́ pe àwọn tí ó mòye nínú wọn.

Ka pipe ipin Jeremáyà 9