Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 51:49-60 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

49. “Gẹ́gẹ́ bí Bábílónì ti mú kí àwọn olùpa Ísírẹ́lì ṣubúbẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní àwọn olùpa gbogbo ilẹ̀ ayé yóò ṣubú.

50. Ẹ̀yin tí ó ti bọ́ lọ́wọ́ idà, ẹ lọ, ẹ má dúró:Ẹ rántí Olúwa ní òkèrè,ẹ sì jẹ́ kí Jérúsálẹ́mù wá sí ọkàn yín.”

51. “Ojú tì wá, nítorí pé àwa ti gbọ́ ẹ̀gàn:ìtìjú ti bò wá lójúnítorí àwọn àlejò wá sórí ohun mímọ́ ilé Olúwa.”

52. “Nítorí náà, wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí,“tí èmi yóò se ìbẹ̀wò lórí àwọn ère fífin rẹ̀:àti àwọn tí ó gbọgbẹ́ yóò sì máa gbin já gbogbo ilẹ̀ rẹ̀

53. Bí Bábílónì tilẹ̀ gòkè lọ sí ọ̀run,bí ó sì ṣe ìlú olodi ní òkè agbára rẹ,síbẹ̀ àwọn afiniṣèjẹ yóò ti ọ̀dọ̀ mi tọ̀ ọ́ wá,”ní Olúwa wí.

54. “Ìró igbe láti Bábílónì,àti ìparun láti ilẹ̀ àwọn ará Kálídéà!

55. Nítorí pé Olúwa ti ṣe Bábílónì ní ìjẹ,ó sì ti pa ohun ńlá run kúrò nínú rẹ̀;rírú wọn sì ń hó bi púpọ̀, a gbọ́ ariwo ohùn wọn.

56. Nítorí pé afiniṣe ìjẹ dé sórí rẹ̀,àní sórí Bábílónì;a mú àwọn akọni rẹ̀, a ṣẹ́ gbogbo ọrun wọn:nítorí Ọlọ́run ẹ̀san ni Olúwa,yóò san án nítòótọ́.

57. Èmi ó sì mú kí àwọn ìjòyè rẹ̀ yó bí ọ̀mùtí,àti àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀àti àwọn alákòóṣo rẹ̀, àti àwọn akọni rẹ̀,wọn ó sì sun oorun láéláé, wọn kì ó sì jí mọ́,”ní Ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa ọmọ ogun.

58. Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ ogun wí:“Odi Bábílónì gbígbòòrò ní a ó wó lulẹ̀ pátapáta,ẹnu bodè gíga rẹ̀ ní a ó sì fi iná sun:tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn ti ṣiṣẹ́ lásán,àti àwọn orílẹ̀-èdè ti ṣiṣẹ́ fún iná,tí àárẹ̀ sì mú wọn.”

59. Ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà wòlíì pàṣẹ fún Seráíyà, ọmọ Néríà, ọmọ Mááséíyà, nígbà tí o ń lọ ni ti Ṣedekáyà, Ọba Júdà, sí Bábílónì ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀. Séráíà yí sì ní ìjòyè ibùdó.

60. Jeremáyà sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ ibi tí yóò wá sórí Bébálì sínú ìwé kan, àní gbogbo ọ̀rọ wọ̀nyí tí a kọ sí Bábílónì.

Ka pipe ipin Jeremáyà 51