Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 14:10-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Báyìí ni Olúwa sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí:“Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri;wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu.Nítorí náà Olúwa kò gbà wọ́n;yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí,yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.”

11. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe gbàdúrà fún àlàáfíà àwọn ènìyàn wọ̀nyí.

12. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbààwẹ̀, èmi kò ní tẹ́tí sí igbe wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rúbọ ọrẹ sísun àti ẹbọ ọkà, èmi ò ní gbà wọ́n. Dípò bẹ́ẹ̀, èmi ó fi idà, ìyànu àti àjàkálẹ̀-àrùn pa wọ́n run.”

13. Ṣùgbọ́n mo sọ pé, “Áà! Olúwa tí ó pọ̀ ní ipá. Wòlíì ń sọ fún wọn pé, ‘ẹ kò rí idà tàbí ìyàn. Dájúdájú èmi ó fún yín ní àlàáfíà tí yóò tọ́jọ́ níbí yìí?’ ”

14. Nígbà náà Olúwa sọ fún mi pé, “Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Èmi kò rán wọn, tàbí yàn wọ́n tàbí bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí sí i yín. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín nípa ìran ìrírí, àfọ̀ṣẹ, ìbọ̀rìṣà àti ìtànjẹ ọkàn wọn.

15. Nítorí náà, èyí ni Olúwa sọ nípa àwọn wòlíì tí wọ́n ń sọ àṣọtẹ́lẹ̀ lórúkọ mi. Èmi kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n sì ń sọ pé, ‘idà kan tàbí ìyàn, kì yóò dé ilẹ̀ yìí.’ Àwọn wòlíì kan náà yóò parẹ́ nípa idà àti ìyàn.

16. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ni a ó lé sí òpópónà Jérúsálẹ́mù torí idà àti ìyàn. Wọn kò ní i rí ẹni tí yóò sìn wọ́n tàbí ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. Èmi yóò mú ìdààmú tí ó yẹ bá ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.

17. “Sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn báyìí pé:“ ‘Jẹ́ kí omijé dà lójú milọ́sàn-án àti lóru láìdúró.Fún wúndíá mi-àwọn ènìyàn mití a dá lọ́gbẹ́ àti lílù bolẹ̀.

18. Bí mo bá lọ sí orílẹ̀ èdè náà,Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa.Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá,èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn.Wòlíì àti Àlùfáàti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.’ ”

19. Ṣé o ti kọ Júdà sílẹ̀ pátapáta ni?Ṣé o ti sá Síónì tì?Èéṣe tí o fi pọ́n wa lójútí a kò fi le wò wá sàn?A ń retí àlàáfíàṣùgbọ́n ohun rere kan kò tí ì wá,ní àsìkò ìwòsànìpáyà là ń rí.

20. Olúwa, a jẹ́wọ́ ìwà ibi waàti àìṣedédé àwọn baba wa;lóòótọ́ ni a ti ṣẹ̀ sí ọ.

21. Nítorí orúkọ rẹ má ṣe kórìíra wa;má ṣe sọ ìtẹ́ ògo rẹ di àìlọ́wọ̀.Rántí májẹ̀mú tí o bá wa dákí o má ṣe dà á.

Ka pipe ipin Jeremáyà 14