Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 5:10-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Nítorí náà láàrin rẹ àwọn baba yóò má a jẹ ọmọ wọn, àwọn ọmọ náà yóò máa jẹ baba wọn. N ó jẹ ọ́ níyà, n ó sì tú àwọn tó bá ṣẹ́kù ká sínú èfúùfù.

11. Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run wí pé, bí mo ṣe wà láàyè, nítorí pé o ti sọ ibi mímọ́ mi di àìmọ́ pẹ̀lú àwọn àwòrán ẹ̀gbin àti àwọn ohun ìríra rẹ, n ó mú ojú rere mi kúrò lára rẹ n kò ní í da ọ sí tàbí wò ọ́ pẹ̀lú àánú mọ́.

12. Ìdá mẹ́ta nínú àwọn ènìyàn rẹ yóò kú nípa àjàkálẹ̀-àrùn tàbí kí ìyàn run wọ́n: ìdá mẹ́ta yóò ṣubú nípa idà lẹ́yìn odi rẹ n ó sì tú ìdá mẹ́ta yóòkù ká sínú èfúùfù, a ó sì máa fi idà lé wọn.

13. “Ìbínú mi yóò sì dúró, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú gbígbónná mi yóò sì rolẹ̀, n ó sì ti gba ẹ̀san mi. Nígbà tí mo bá sì parí ìbínú mi lórí wọn, wọn ó mọ̀ pé Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀ nínú ìtara mi.

14. “Èmi yóò fi ọ́ ṣòfò, ó sì sọ ọ́ di ẹ̀gàn fún àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká, àti lójú àwọn tó ń kọjá

15. O ó wá di ẹ̀gàn, ẹ̀sín àti ikílọ àti ohun ẹ̀rù àti ìyanu fún àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká nígbà tí mo bá fìyà jẹ ọ́ nínú ìbínú àti nínú ìbínú gbígbóná mi. Èmi Olúwa ni ó sọ bẹ́ẹ̀.

16. Nígbà tí mo bá ta ọfà ikú àti ìparun pẹ̀lú ìyàn, n ó ta á láti run ọ́ ni. N ó gé ìpèsè oúnjẹ kúrò, n ó sì mú ìyàn wá lọ́pọ̀lọpọ̀.

17. Èmi yóò rán ìyàn àti ẹranko búburú sí i yín, wọn yóò fi yín sílẹ ni àìlọ́mọ. Àjàkálẹ̀ àrùn àti ìtàjẹ̀-sílẹ̀ yóò kọjá láàrin yín. Èmi yóò si mú idà wá sórí rẹ. Èmi Olúwa ló sọ bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 5