Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 47:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọkùnrin náà mú mi padà lọ sí àbáwọlé tẹ́ḿpìlì náà, mo sì rí omi tí ó ń tú jáde láti abẹ́ ìloro tẹ́ḿpìlì náà sí apá ìhà ìlà oòrùn (nítorí tẹ́ḿpìlì náà dojúkọ ìhà ìlà oòrùn) Omi náà ń tú jáde sí ìsàlẹ̀ láti abẹ́, ní ìhà gúsù tẹ́ḿpìlì náà, ní ìhà gúsù pẹpẹ.

2. Ó wá mú mi gba ojú ọ̀nà àríwá jáde, ó sì mú mi yí ìta ojú ọ̀nà ìta tí ó dojúkọ ìhà ìlà oòrùn, omi náà sì ń ṣàn láti ìhà gúsù wá.

3. Bí ọkùnrin náà ti lọ sí apá ìhà ìlà oòrùn pẹ̀lú okùn wíwọ̀n nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀, o wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́, ó sì mú mi gba ibi odò kan tí kòì jìnjù kókósẹ̀ lọ.

4. Ó sì wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ó sì mú mi gba ibi odò tí o jìn ní ìwọ̀n orúnkún. Ó tún wọn ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ó sì mú mi gba odò tí ó dé ìbàdí.

5. Ó wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ṣùgbọ́n nísinsìnyí odò tí ń kò lè kọjá rẹ̀ ni, Nítorí pé odò tí ó kún, ó sì jìn tó èyí tí wọ́n le lúwẹ̀ẹ́ nínú rẹ̀ odò tí ẹnikẹ́ni kò le dá kọjá ni.

6. Ó bi mí léèrè, pé: “Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ o rí èyí?”Lẹ́yìn náà ó mú mi padà sí etí odò.

7. Nígbà tí mo dé ibẹ̀, mo rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì odò.

8. Ó sọ fún mi pé, “Odò yìí ń ṣàn sí ìhà ìlà oòrùn, ó sì lọ sí ìsàlẹ̀ títí dé Árábù, níbi tí ó ti wọ inú òkun, omi tí o wà níbẹ̀ jẹ́ èyí tí ó tutù.

9. Àwọn ohun alààyè tí o ń rákò yóò máa gbé ní íbikíbi tí odò ti ń ṣàn. Ẹja yóò pọ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀, nítorí pé odò ń ṣàn síbẹ̀ ó sì mú kí omi iyọ̀ tutù nini; nítorí náà níbi tí omi ti ń ṣàn gbogbo nǹkan ni yóò wà ni ààyè.

10. Àwọn apẹja yóò dúró ní etí bèbè odò; láti Éńgédì títí dé Énégíláémù àyè yóò wa láti tẹ́ àwọ̀n wọn sílẹ̀. Orísìírísìí ẹja ni yóò wà gẹ́gẹ́ bí ẹja omi òkun ńlá.

11. Ṣùgbọ́n ẹrẹ̀ àti àbàtà kò ní tòrò; àwa yóò fi wọn sílẹ̀ fún iyọ̀.

12. Àwọn igi eléso ní oríṣìíríṣìí ni yóò dàgbà ní bèbè odò méjèèjì. Ewé wọn kì yóò sì gbẹ, tàbí ní èso nítorí pé odò láti ibi mímọ́ ń ṣàn sí wọn. Èso wọn yóò dàbí oúnjẹ àti ewé wọn fún ìwòsàn.”

13. Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Ọba wí: “Ìwọ̀nyí ni àwọn ààlà tí ìwọ yóò fi pín ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ogún ìní ní àárin àwọn ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì, pẹ̀lú ìpín méjì fún Jóṣéfù.

14. Ìwọ yóò pín ilẹ̀ náà déédéé ní àárin wọn. Nítorí pé mo búra nípa nína ọwọ́ sókè láti fi fún àwọn baba ńlá yin, ilẹ̀ yìí yóò di ogún ìní yín.

15. “Èyí yìí ni yóò jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà:“Ní ìhà àríwá yóò lọ láti omi òkun ńlá ní ibi ọ̀nà Hétílónì gbà tí Hámátì sí Sídádì,

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 47