Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 45:2-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Lára èyí, apákan ti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan tí o jẹ́ ẹ̀ẹ́dégbẹ̀ta ìgbọ̀nwọ́ ní ó gbọdọ̀ wà fún ibi ìyàsímúmọ́ fún Ọlọ́run, pẹ̀lú ibẹ̀ tí ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ fún ilẹ̀ tí ó yí ibi mímọ́ náà ká. Ilẹ̀ tí ó yí i ká yìí yóò wà bẹ́ẹ̀ láì lò ó.

3. Ní agbègbè ibi mímọ́, wọn ya ibi kan sọ́tọ̀ kí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní fífẹ̀. Ní inú rẹ ni ilẹ̀ ti a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa yóò wà, ìyẹn ibi mímọ́ jùlọ.

4. Yóò jẹ́ ibi mímọ́ lára ilẹ̀ náà fún àwọn àlùfáà, tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ibi mímọ́ àti àwọn tí ó súnmọ́ àlùfáà ní iwájú Olúwa. Ibẹ̀ yóò jẹ ibi tí yóò wà fún ilé gbígbé wọn, bákan náà ni yóò jẹ́ ibi mímọ́ fún ilé Olúwa.

5. Agbègbè kan tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní fífẹ̀ yóò jẹ́ ti àwọn ará Léfì, tí ó ń ṣiṣẹ ìránṣẹ́ nínú tẹ́ḿpìlì, gẹ́gẹ́ bi ìní wọn fún ìlú wọn láti máa gbé ibẹ̀.

6. “ ‘Ìwọ yóò fi ìlú náà ti agbègbè rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀ àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, papọ̀ mọ́ ibi mímọ́ fún àwọn ilé Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìní: yóò jẹ́ ti gbogbo ilé Ísírẹ́lì.

7. “ ‘Àwọn ọmọ aládé ni yóò bá ibi mímọ́ pààlà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan agbégbé tí ó jẹ ibi mímọ́ àti ohun tí ó jẹ́ ti ìlú. Yóò fẹ̀ sẹ́yìn sí ìhà ìwọ̀ oòrùn láti apá ìwọ̀ oòrùn àti si ìlà oòrùn, láti apá ìlà oòrùn, gígùn rẹ̀ yóò jẹ́ láti ìwọ̀ oòrùn sí ààlà ìlà oòrùn, ti ìṣe déédéé rẹ̀ yóò jẹ́ ti ọ̀kan lára àwọn ìpín ẹ̀yà.

8. Ilẹ̀ yìí ni yóò jẹ́ ìpín rẹ̀ ní Ísírẹ́lì. Àwọn ọmọ aládé mìíràn kò ní rẹ́ àwọn ènìyàn mi jẹ mọ́, ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ kí àwọn ilé Ísírẹ́lì gba ilẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bi ẹ̀yà wọn.

9. “ ‘Èyí yìí ni Olúwa Ọba wí: Ìwọ ti rìn jìnnà tó, Ẹ̀yin ọmọ aládé tí Ísírẹ́lì! Fi ìwà ipá àti ìrẹ́jẹ rẹ sílẹ̀ kí ó sì se èyí tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ. Dáwọ́ gbígbà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn mi dúró, ni Olúwa Ọba sọ.

10. Ìwọ gbọdọ̀ lo òṣùnwọ̀n tó tọ́ àti efà títọ́ àti bátì títọ́.

11. Éfà àti batì gbọdọ̀ jẹ́ bákan náà, kí bátì tí ó gba ìdàmẹ́wàá hómérì, àti ẹfa ìdámẹ́wàá hómérì: Hómérì ni kí ó jẹ́ òṣùnwọ̀n tí wọn yóò lò fún méjèèjì.

12. Ṣékélì ní kí o gba ogún gérà. Ogún ṣekeli pẹ̀lú ṣékélì márùndínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú ṣékélì mẹ́ẹ̀dógún yóò jẹ́ mínà kan.

13. “ ‘Èyí yìí ni ẹ̀bùn pàtàkì tí o gbọdọ̀ ṣe: éfà kẹ́fà láti inú hómérì ọkà kọ̀ọ̀kan àti éfà kẹ́fà láti inú hómérì báálì kọ̀ọ̀kan.

14. Ìpín òróró tí a júwe, tí a fi bátì wọ̀n, ni ìdámẹ̀wàá bátì láti inú kórì (èyí tí ó gba ìdámẹ́wàá bati tàbí hómérì kan, fún ìdámẹ̀wàá bátì jẹ́ bákan náà sì hómérì kan.)

15. Bákan náà ni àwa yóò mú àgùntàn kan láti inú agbo ẹran tí ó jẹ́ igba láti inú kanga omi pápá oko tútù tí Ísírẹ́lì. Ìwọ̀nyí ni wọn yóò lò fún àwọn ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ẹbọ sísun àti ìdàpọ̀ ọrẹ ẹbọ láti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún àwọn ènìyàn, ní Olúwa Ọba sọ.

16. Gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà ni yóò kópa nínú ẹ̀bùn pàtàkì fún ìlò àwọn ọmọ aládé ni Ísírẹ́lì.

17. Yóò jẹ́ ojúṣe ọmọ aládé láti pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti ọrẹ ẹbọ mímu níbi àṣè gbogbo, ti oṣù tuntun àti ní àwọn ọjọ ìsìnmi ni gbogbo àjọ ilé Ísírẹ́lì. Oun yóò pèsè ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀, láti ṣe ètùtù fún ilé Ísírẹ́lì.

18. “ ‘Èyí yìí ní Olúwa Ọba wí: Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní ìwọ yóò mú akọ màlúù aláìlábàwọ́n kì o sì sọ ilé Ọlọ́run di mímọ́.

19. Àlùfáà ni yóò mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí o sì fi si ẹnu ilẹkùn ilé Ọlọ́run, àti sí ara àwọn ilẹ̀kùn tí ó wà ní àgbàlá ti inú.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 45