Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 43:7-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ó sì wí pé: “Ọmọ ènìyàn, èyí yìí ni ibi ìgunwà mi àti ibi tí ó wà fún àtẹ́lẹsẹ̀ mi, Ibi yìí ni èmi yóò máa gbé ní àárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí láéláé. Ilé Ísírẹ́lì kò ní ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́ láéláé àwọn tàbí àwọn Ọba wọn nípa àgbèrè àti àwọn ère aláìlẹ́mìí àwọn Ọba wọn ní ibi gíga.

8. Nígbà tí wọ́n ba gbé ìlóro ilé wọn kangun sí ìlóro ilé mi àti ìlẹ̀kùn wọn sì ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀kùn mi, pẹ̀lú ògiri nìkan ní àárin èmi pẹ̀lú wọn, wọ́n ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú ìwà ìríra wọn. Nígbà náà ni mo pa wọ́n run ní ìbínú mi.

9. Nísinsin yìí jẹ́ kí wọn mú ìwà àgbérè wọn àti àwọn ère aláìlẹ́mìí àwọn Ọba wọn kúrò ni iwájú mi, èmi yóò sì gbé àárin wọn láéláé.

10. “Ọmọ ènìyàn, ṣàpèjúwe ilé Ọlọ́run náà fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì kí ojú ẹ̀ṣẹ̀ wọn, lè tì wọ́n sì jẹ́ kí wọn wo àwòrán ilé náà,

11. tí ojú gbogbo ohun tí wọn ti ṣe bá tì wọ́n, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ àwòrán ilé Ọlọ́run náà bí wọ́n ṣe tò ó lẹ́sẹẹsẹ, àbájáde àti àbáwọlé rẹ̀ gbogbo àwòrán àti gbogbo òfin àti ìlànà rẹ̀. Kọ ìwọ̀nyí sílẹ̀ ní iwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ́ olóòtọ́ si àwòrán rẹ̀, kí wọ́n sì tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀.

12. “Èyí yìí ní òfin ilé Ọlọ́run náà: Gbogbo àyíká lórí òkè gíga ní yóò jẹ́ ibi mímọ́ jùlọ. Bí èyí ni òfin tẹ́ḿpìlì náà.

13. “Ìwọ̀nyí ni wíwọ̀n pẹpẹ ìrúbọ ní gígùn ìgbọ̀nwọ́, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni jíjìn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni fífẹ̀, igun rẹ̀ yípo àti etí rẹ̀ jẹ́ ibú àtẹ́lẹwọ́ kan: Èyí yìí sì ni gíga pẹpẹ ìrúbọ náà:

14. Láti ìsàlẹ̀ rẹ̀ ni ilẹ̀ títí dé ìsàlẹ̀ igun rẹ̀, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì ni gíga o sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀:

15. Ibi ìdáná pẹpẹ ìrúbọ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gíga, ìwo mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì yọrí jáde sókè láti ibi ìdáná.

16. Ibi ìdáná pẹpẹ náà jẹ́ igun mẹ́rin mẹ́rin lọ́gbọgba, ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ní gígùn, o sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ní fífẹ̀.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 43