Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 43:11-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. tí ojú gbogbo ohun tí wọn ti ṣe bá tì wọ́n, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ àwòrán ilé Ọlọ́run náà bí wọ́n ṣe tò ó lẹ́sẹẹsẹ, àbájáde àti àbáwọlé rẹ̀ gbogbo àwòrán àti gbogbo òfin àti ìlànà rẹ̀. Kọ ìwọ̀nyí sílẹ̀ ní iwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ́ olóòtọ́ si àwòrán rẹ̀, kí wọ́n sì tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀.

12. “Èyí yìí ní òfin ilé Ọlọ́run náà: Gbogbo àyíká lórí òkè gíga ní yóò jẹ́ ibi mímọ́ jùlọ. Bí èyí ni òfin tẹ́ḿpìlì náà.

13. “Ìwọ̀nyí ni wíwọ̀n pẹpẹ ìrúbọ ní gígùn ìgbọ̀nwọ́, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni jíjìn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni fífẹ̀, igun rẹ̀ yípo àti etí rẹ̀ jẹ́ ibú àtẹ́lẹwọ́ kan: Èyí yìí sì ni gíga pẹpẹ ìrúbọ náà:

14. Láti ìsàlẹ̀ rẹ̀ ni ilẹ̀ títí dé ìsàlẹ̀ igun rẹ̀, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì ni gíga o sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀:

15. Ibi ìdáná pẹpẹ ìrúbọ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gíga, ìwo mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì yọrí jáde sókè láti ibi ìdáná.

16. Ibi ìdáná pẹpẹ náà jẹ́ igun mẹ́rin mẹ́rin lọ́gbọgba, ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ní gígùn, o sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ní fífẹ̀.

17. Igun ni apá òkè náà jẹ́ igun mẹ́rin lọ́gbọgba, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá ní gígùn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá ní fífẹ̀, pẹ̀lú etí tí ó jẹ́ ìdáji ìgbọ̀nwọ́, ìsàlẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan yípo. Àtẹ̀gùn pẹpẹ ìrúbọ náà dojúkọ ìlà oòrùn.”

18. Lẹ́yìn náà, ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, èyí yìí ni ohun tí Olúwa wí: Ìwọ̀nyí yóò jẹ́ òfin fún ìrúbọ ẹbọ sísun àti wíwọ́n ẹ̀jẹ̀ sórí pẹpẹ nígbà tí a bá mọ pẹpẹ tán:

19. Ẹ̀yin ní láti mú ọ̀dọ́ akọ màlúù gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrékọjá fún àwọn àlùfáà, tí ó jẹ́ Léfì, tí ìdílé Sádókù tí ó wá sí agbègbè láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún mi ní Olúwa Ọba wí.

20. Ẹ ni láti mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí ẹ sì fi sórí ìwo mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà lórí pẹpẹ, àti lórí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ìjòkòó náà àti sí gbogbo etí rẹ̀ yípo, ìwọ yóò sì sọ pẹpẹ di mímọ́, ìwọ yóò sì ṣe ètùtù rẹ̀.

21. Ìwọ gbọdọ̀ mú akọ màlúù fún ìrékọjá, ìwọ yóò sì sun ún ní apá ibi tí a ṣàmì sí ní agbègbè ilé Ọlọ́run ní ìta ibi mímọ́.

22. “Ní ọjọ́ kejì ìwọ yóò fi ewúrẹ́, òbúkọ aláìlábàwọ́n fún ẹbọ ẹsẹ, a sì gbọdọ̀ sọ pẹpẹ di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí a ti sọ́ di mímọ́ pẹ̀lú akọ màlúù.

23. Nígbà tí ìwọ bá parí ìsọdimímọ́, ìwọ yóò fi ọ̀dọ́ akọ màlúù àti ọ̀dọ́ àgbò aláìlábàwọ́n láti inú agbo fún ìrúbọ.

24. Ìwọ yóò mú wọn lọ sí iwájú Olúwa, àwọn àlùfáà ni yóò fi iyọ̀ wọ́n wọn, wọn yóò sì fi wọ́n rúbọ sísun sí Olúwa.

25. “Fún ọjọ́ méje, ìwọ ní láti pèsè akọ ewúrẹ́ kan lójoojúmọ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; Ìwọ yóò sì pèsè ọ̀dọ́ akọ màlúù àti àgbò láti inú agbo, méjèèjì yóò sì jẹ́ aláìlábàwọ́n.

26. Fún ọjọ́ méje wọn yóò jẹ́ ètùtù fún pẹpẹ, wọn yóò sì sọ ọ́ di mímọ́; nípa bẹ́ẹ̀ wọn yóò yà á sọ́tọ̀.

27. Ní ìparí ọjọ́ wọ̀nyí, láti ọjọ́ mẹ́jọ síwájú, àwọn àlùfáà ni yóò gbé àwọn ẹbọ sísun rẹ àti ẹbọ ìdàpọ̀ rẹ̀ kalẹ̀ lórí pẹpẹ. Lẹ́yìn náà, èmi yóò tẹ́wọ́gba yín ní Olúwa Ọba wí.”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 43