Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 40:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kẹẹdọ́gbọ̀n tí a ti wà ni oko ẹrú wa, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún, ni oṣù kẹwàá ọdún kẹ́rinlá lẹ́yin ìsubú ìlú ńlá náà ní ọjọ́ náà gan an ọwọ́ Olúwa ń bẹ̀ lára mi, oùn sì mú mi lọ síbẹ̀.

2. Nínú ìran Ọlọ́run, ó mú mí lọ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ó sì gbé mi lọ sí orí òkè gíga fíofío. Ní ẹ̀gbẹ́ gúsù ọ̀pọ̀ ilé tó wà níbẹ̀ dàbí ìlú ńlá.

3. Ó mú mi lọ síbẹ̀, mo sì rí ọkùnrin kan tí ìrírí rẹ̀ dàbí ìrí bàba; ó dúró ni ẹnu ọ̀nà pẹ̀lú okùn aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun àti ọ̀pá ìwọnlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀.

4. Ọkùnrin náà sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, wò pẹ̀lú ojú rẹ kí o sì gbọ́ pẹ̀lú etí rẹ, kí ó sì farabalẹ̀ sì gbogbo ohun tí mo máa fi hàn ọ, nítorí ìdí nìyí tí a fi mú ọ wá síhìn-ín. Sọ gbogbo ohun tí ó bá rí fún ilé Ísírẹ́lì.”

5. Mo rí ògiri tí ó yí agbègbè ibi mímọ̀ po. Gígùn ọ̀pá ìwọnlẹ̀ tí ó wà ní ọwọ́ ọkùnrin náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà, ọkọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ilásì mẹ́rin ẹsẹ̀ bàtà. Ó wọn ògiri náà; ó jẹ́ ìwọ̀nyí ọ̀pá náà ni níní ipọn, ó sì jẹ́ ọ̀pá kan ní gíga.

6. Lẹ́yìn náà ni ó wá lọ sí ẹnu ọ̀nà òde tí ó kọjú sí ìlà òòrùn. Ó gun àtẹ̀gùn rẹ̀, o sì wọn ìloro ẹnu ọ̀nà ilé; ó jẹ́ ọ̀pa kan ní jíjìn.

7. Yàrá kéékèèkéé sì jẹ ọ̀pá kan ni gígùn àti ọpá kan ní ibú, ìgbéró ògiri àárin yàrá kéékèèkéé náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni nínípọn. Ìloro ẹnu ọ̀nà náà tí ó kángun sí àtẹ̀wọ́ ẹnu ọ̀nà náà tó kọjú sì tẹ́ḿpìlì jẹ́ ọ̀pá kan ní jíjìn.

8. Lẹ́yìn náà, ó wọn àtẹ̀wọ́ ẹnu ọ̀nà:

9. Ó jẹ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ ní jíjìn àtẹ́rígbà rẹ̀ sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ méjì ní nínípọ̀n. Àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà kọjú sí tẹ́ḿpìlì.

10. Ní ẹnu ọ̀nà ìlà òòrùn ni àwọn yàrá kéékèèkéé mẹ́ta wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan: mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kọ̀ jú sí ara wọn, ojú ìgbéró ògiri ni ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ bákan náà ní wíwọ̀n.

11. Lẹ́yìn náà ó wọn ìbú à bá wọ ẹnu ọ̀nà náà; ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wà, gígùn rẹ̀ sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́tàlá.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 40