Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 37:16-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. “Ọmọ ènìyàn, mú igi pátakó kan kí ó sì kọ̀wé sí ara rẹ̀, ‘Tí ó jẹ́ ti Júdà àti ti Ísírẹ́lì tí ó ní àsṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.’ Lẹ́yìn náà, kí ó mú igi pátakó mìíràn kí ó sì kọ̀wé sí ara rẹ̀, ‘Igi tí Éfúraímù jẹ́ ti Jósẹ́fù àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì tí ó ni àṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.’

17. So wọ́n papọ̀ sí ara igi kan nítorí náà wọn yóò di ọ̀kan ní ọwọ́ rẹ.

18. “Nígbà tí àwọn ara ìlú rẹ bá béèrè lọ́wọ́ rẹ pé, ‘Ṣé ìwọ kò ní sọ ohun tí èyí túmọ̀ sí fún wa?’

19. Ṣọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi yóò gba igi Jósẹ́fù—èyí tí ó wà ní ọwọ́ Éfúráímù—àti ti ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí ó parapọ̀ mọ́ ọn, kí ó sì só papọ̀ mọ́ igi Júdà, láti sọ wọ́n di igi kan ṣoṣo, wọn yóò sì di ọ̀kan ní ọwọ́ mi.’

20. Gbé igi pátakó tí ó kọ nǹkan síi sókè ní iwájú wọn,

21. kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi yóò mú Ísírẹ́lì jáde kúrò ní àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti lọ. Èmi yóò ṣà wọ́n jọ pọ̀ láti gbogbo agbègbè, èmi yóò sì mú wọn padà sí ilẹ̀ ara wọn.

22. Èmi yóò ṣe wọ́n ní orílẹ̀ èdè kan ní ilẹ̀ náà, ní orí òkè Ísírẹ́lì, Ọba kan ni yóò wà lórí gbogbo wọn, wọn kì yóò sì jẹ́ orílẹ̀ èdè méjì mọ́, tàbí kí a pín wọn sí ìjọba méjì.

23. Wọn kì yóò sì tún fi àwọn òrìṣà wọn ba ara wọn jẹ́ mọ́, tàbí ohun ìríra wọn, tàbí ohun ìrékọjá wọn: ṣùgbọ́n èmi yóò gbà wọn là kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àgàbàgebè wọn, èmi yóò sì wẹ̀ wọn mọ́. Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.

24. “ ‘Dáfídì ìránṣẹ́ mi ni yóò jẹ Ọba lórí wọn, gbogbo wọn yóò sì ní olùṣọ àgùntàn kan. Wọn yóò sì tẹ̀lé òfin mi, wọn yóò sì ṣe àníyàn láti pa àṣẹ mi mọ́.

25. Wọn yóò gbé ní ilẹ̀ tí mo fún Jákọ́bù ìránṣẹ́ mi, ilẹ̀ tí àwọn baba yín ń gbé. Àwọn àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ọmọ ọmọ wọn ni yóò máa gbé ibẹ̀ láéláé, Ìránṣẹ́ mi Dáfídì ni yóò jẹ́ ọmọ Aládé wọn láéláé.

26. Èmi yóò dá májẹ̀mu àlàáfíà pẹ̀lú wọn, yóò sì jẹ́ májẹ̀mu títí ayérayé. Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀, èmi yóò sì ṣọ wọ́n di púpọ̀ ní iye, èmi yóò sì gbé ilé mímọ́ mi kalẹ̀ ní àárin wọn títí láé.

27. Ibùgbé mí yóò wà pẹ̀lú wọn, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.

28. Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀ èdè yóò mọ̀ pé, èmi Olúwa ṣọ Ísírẹ́lì di mímọ́, nígbà tí ibi mímọ́ mi bá wà ní àárin wọn títí ayérayé.’ ”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 37