Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 32:21-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Láti inú isà òkú alágbára tí í ṣe aṣáájú yóò sọ nípa Éjíbítì àti àwọn àlejò rẹ̀, ‘Wọn ti wá sí ìsàlẹ̀, wọn sì sùn pẹ̀lú aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.’

22. “Ásíríà wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo jagun jagun rẹ̀; àwọn isà òkú àwọn tí a ti pa sì yí i ká, gbogbo àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú.

23. Isà òkú wọn wà ní ibi tí ó jìnlẹ̀ gan an nínú kòtò. Gbogbo àwọn tí ó ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè ní a pa, tí ó ti ipa idà ṣubú.

24. “Élámù wà níbẹ̀, o yí isà òkú rẹ̀ ká pẹ̀lú gbogbo ijọ rẹ̀. Gbogbo wọn ni a pa, àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú. Gbogbo àwọn tí ó ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè lọ sí ìsàlẹ̀ láìkọlà sí abẹ́ ilẹ̀. Wọ́n gba ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò.

25. A ṣe ibùsùn fún un láàárin àwọn tí a pa, pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀ tí ó yí isà òkú ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, tí a fi idà pa. Nítorí pé a tan ẹ̀rù wọn ká ilẹ̀ alààyè, wọn ru ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò; a tẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn tí a pa.

26. “Méṣékì àti Túbálì wà níbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìjọ wọn yí isà òkú wọn ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, wọ́n fi idà pa wọ́n nítorí ẹ̀rù ti wọn tàn ká ilẹ̀ alààyè.

27. Ṣé wọn kò sùn pẹ̀lú àwọn ọ̀gágun aláìkọlà tí ó ti ṣubú, tí o lọ sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú ohun ìjà, tí a sì fi idà wọn sí ìgbérí wọn? Ìjìyà fún ẹ̀sẹ̀ wọn sinmi ní orí egungun wọn, ẹ̀rù àwọn ọ̀gágun ti wà káàkiri ilẹ̀ alààyè.

28. “Ìwọ náà, Fáráò, ní yóò ṣẹ, ti yóò dùbúlẹ̀ láàárin aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.

29. “Édómù wà níbẹ̀, àwọn Ọba rẹ̀ àti gbogbo ọmọbìnrin Ọba; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní agbára, a tẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa. Wọn dùbúlẹ̀ pẹ̀lú aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn ti o lọ sínú kòtò.

30. “Gbogbo àwọn ọmọ aládé ilẹ̀ àríwá àti gbogbo àwọn ará Sídónì wà níbẹ̀; wọn lọ sí ìsàlẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí a pa ní ìtìjú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ṣe okùnfà ẹ̀rù pẹ̀lú agbára wọn. Wọn sùn ní àìkọlà pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa, wọn sì ru ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò.

31. “Fáráò, òun àti gbogbo jagunjagun rẹ̀ óò rí wọn, a yóò sì tù ú nínú nítorí gbogbo ìjọ rẹ̀ tí a fi idà pa, ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

32. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè, Fáráò àti gbogbo ìjọ rẹ̀ ni a óò tẹ́ sí àárin aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 32