Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 30:12-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Èmi yóò mú kí àwọn odò Náílì gbẹÈmi yóò sì ta ilẹ náà fún àwọn ènìyàn búburú:láti ọwọ́ àwọn àjòjì ènìyànÈmi yóò jẹ́ kí ilẹ̀ náà àti gbogbo ohun tí ó wá nínú rẹ ṣòfò.Èmi Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

13. “ ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Èmi yóò pa àwọn òrìṣà runÈmi yóò sì mú kí òpin dé báère òrìṣà gbígbẹ́ ni Nófìkò ní sí ọmọ aládé mọ́ ní Éjíbítì,Èmi yóò mú kí ìbẹ̀rù gba gbogbo ilẹ̀ náà.

14. Èmi yóò sì mú kí Pátírọ́sì di ahoroèmi yóò fi ina sí Sóánìèmi yóò sì fi ìyà jẹ Tébésì

15. Èmi yóò tú ìbínú mi jáde sórí Pélúsíómùìlú odi Éjíbítìèmi yóò sì ké àkójọpọ̀ Jépésì kúrò

16. Èmi yóò ti iná bọ ÉjíbítìPélúsíómù yóò japoró ní ìroraÈfúùfù yóò jà ní TébésìMémìfísì yóò wà ìpọ́njú ní ìgbà gbogbo

17. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ní Hẹ́lópónísè àti Búbásítìyóò ti ipa idà subúwọn yóò sì kó àwọn ìlú wọn ní ìgbèkùn

18. Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tápárebìnígbà tí mo bá já àjàgà Éjíbítì kúrò;níbẹ̀ agbára iyì rẹ̀ yóò dópinwọn yóò fi ìkùukùu bò óàwọn abúlé rẹ ní wọn yóò lọ sí ìgbèkùn.

19. Nítorí náà Èmi yóò mú ki ìjìyà wá sórí Éjíbítì,wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”

20. Ní ọjọ́ keje osù kìn-ín-ní ọdún kọkànlá ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

21. “Ọmọ ènìyàn, Èmi ti ṣe apa Fáráò Ọba Éjíbítì. A kò ì tí ì di apá náà papọ̀ láti mu kí ó san, a ko sì ti di i si àárin igi pẹlẹbẹ kí o lè ni agbára tó láti di idà mú.

22. Nítorí náà, báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi lòdì sí Fáráò Ọba Éjíbítì. Èmi yóò sẹ́ apá rẹ̀ méjèèjì, èyí tí ó dára àti èyí tí a ti ṣẹ́ pẹ̀lú, yóò sì mú kí idà bọ́ sọnù ní ọwọ́ rẹ̀.

23. Èmi yóò sì fọ́n àwọn ènìyàn Éjíbítì ká sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì tú wọn ká gbogbo ilẹ̀.

24. Èmi yóò mú kí apá Ọba Bábílónì ní agbára, èmi yóò sì fi idà mi sí ọwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò ṣẹ́ apá Fáráò, yóò sì kérora níwájú rẹ̀ bí ọkùnrin tí a ṣá ní àṣápa.

25. Èmi yóò mú kí apá Ọba Bábílónì lé, ṣùgbọ́n apá Fáráò yóò sì rọ. Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá mú idà mi sí ọwọ́ Ọba Bábílónì yóò sì fí idà náà kọlu Éjíbítì.

26. Èmi yóò fọ́n àwọn ara Éjíbítì ká sí àárin orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sí àárin orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sí gbogbo ilẹ̀. Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 30