Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremáyà 2:10-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Àwọn àgbààgbà ọmọbìnrin Síónìjókòó sílẹ̀ ní ìdákẹ́rọ́rọ́;wọ́n da eruku sí orí wọnwọ́n sì wọ aṣọ àkísà.Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Jérúsálẹ́mùti tẹrí wọn ba sí ilẹ̀.

11. Ojú mi kọ̀ láti sunkún,mo ń jẹ ìrora nínú mi,mo tú ọkàn mi jáde sí ilẹ̀nítorí a pa àwọn ènìyàn mí run,nítorí àwọn ọmọdé àti ọmọ ọwọ́ ń kúní òpópó ìlú.

12. Wọ́n wí fún àwọn ìyá wọn,“Níbo ni àkàrà àti wáìnì wà?” Wò óbí wọ́n ṣe ń kú lọ bí àwọn ọkùnrin tí a ṣe léṣení àwọn òpópónà ìlú,bí ayé wọn ṣe ń ṣòfòláti ọwọ́ ìyá wọn.

13. Kí ni mo le sọ fún ọ?Pẹ̀lú u kí ni mo lè fi ọ́ wé,Ìwọ ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù?Kí sì ni mo lè fi ọ́ wé,kí n lè tù ọ́ nínú,Ìwọ wúndíá bìnrin Síónì?Ọgbẹ́ rẹ jìn bí òkun.Ta ni yóò wò ọ́ sàn?

14. Ìran àwọn wòlíì rẹjẹ́ kìkì ẹ̀tàn láìní ìwọ̀n;wọn kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàntí yóò mú ìgbèkùn kúrò fún ọ.Àwọn òrìṣà tí wọ́n fún ọjẹ́ èké àti ìsìnà.

15. Àwọn tí ó gba ọ̀nà ọ̀dọ̀ rẹpàtẹ́wọ́ lé ọ lórí;wọ́n kẹ́gàn wọ́n ju orí wọnsí ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù:“Èyí ha ni ìlú tí à ń pè níàṣepé ẹwà,ìdùnnú gbogbo ayé?”

16. Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ la ẹnu wọngbòòrò sí ọ;wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì payín kekewọ́n wí pé, “A ti gbé e mì tán.Èyí ni ọjọ́ tí a ti ń retí;tí a sì wá láti rí.”

17. Olúwa ti ṣe ohun tí ó pinnu;ó ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,tí ó sì pàṣẹ ní ọjọ́ pípẹ́.Ó ti sí ọ nípò láì láàánú,ó fún ọ̀tá ní ìsẹ́gun lórí rẹ,ó ti gbé ìwo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ga.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremáyà 2