Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 4:6-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Nígbà náà, ni mo pàṣẹ pé kí a mú gbogbo àwọn amòye Bábílónì wá, kí wọn wá sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi.

7. Nígbà tí àwọn onídán, àwọn apògèdè, àwọn awòràwọ̀ àti àwọn aláfọ̀ṣẹ wá, mo sọ àlá náà fún wọn, ṣùgbọ́n wọn kò le è sọ ìtúmọ̀ àlá náà fún mi.

8. Ní ìkẹyìn Dáníẹ́lì wá síwájú mi, mo sì sọ àlá náà fún (ẹni tí à ń pè ní Beliteṣáṣárì gẹ́gẹ́ bí orúkọ òrìṣà mi àti pé ẹ̀mí àwọn Ọlọ́run mímọ́ wà nínú un rẹ̀.)

9. Mo wí pé, “Beliteṣásárì, olórí àwọn amòye, èmi mọ̀ wí pé ẹ̀mí Ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ, kò sì sí àsírí kan tí ó ṣòro jù fún ọ. Sọ àlá mi kí o sì túmọ̀ rẹ̀ fún mi.

10. Èyí ni ìran náà tí mo rí nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, mo rí igi kan láàrin ayé, igi náà ga gidigidi.

11. Igi náà tóbi, ó sì lágbára, orí i rẹ̀ sì ń kan ọ̀run; a sì rí i títí dé òpin ayé.

12. Ewé e rẹ̀ lẹ́wà, èso rẹ̀ sì pọ̀, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn. Abẹ́ ẹ rẹ̀ ni àwọn ẹranko igbó fi ṣe ibùgbé, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé ní ẹ̀ká rẹ̀, nínú rẹ̀ ni gbogbo alààyè ti ń jẹ.

13. “Lórí ibùsùn mi, mo rí ìran náà, olùṣọ́ kan dúró ṣíwájú u mi, àní ẹni mímọ́ kan, ó ń bọ̀ wá láti ọ̀run

14. ó kígbe sókè wí pé, ‘Gé igi náà kí o sì gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò; gbọn ewé ẹ rẹ̀ ká, kí o sì fọ́n èṣo rẹ̀ dànù. Jẹ́ kí àwọn ẹranko tí ó wà lábẹ́ ẹ rẹ̀ sá àti àwọn ẹyẹ tí ó wà ní ẹ̀ka rẹ̀ kúrò.

15. Ṣùgbọ́n fi kùkùté àti gbòǹgbò o rẹ̀ tí a fi irin àti idẹ dè ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ àti sí orí i koríko igbó.“ ‘Jẹ́ kí ìrì ọ̀run ṣẹ̀ sí i lára, kí ó sì jẹ́ kí ìpín in rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn ẹranko igbó láàrin ilẹ̀ ayé.

16. Jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ kí ó yí padà kúrò ní ti ènìyàn, kí a sì fún un ní ọkàn ẹranko, títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí i rẹ̀.

17. “ ‘Olùṣọ́ ni ó gbé ìpinnu náà jáde, àṣẹ sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹni mímọ́, kí gbogbo alààyè le mọ̀ wí pé, Ọ̀gá Ògò ni olórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹnikẹ́ni tí ó wù ú, òun sì ń gbé onírẹ̀lẹ̀ lórí i wọn.’

18. “Èyí ni àlá tí èmi Nebukadinéṣárì ọba lá. Ní ìsinsìn yìí ìwọ Beliteṣáṣárì, sọ ohun tí ó túmọ̀ sí fún mi, nítorí kò sí amòye kan ní ìjọba mi, tí ó lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi. Ṣùgbọ́n ìwọ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀, nítorí tí ẹ̀mí Ọlọ́run mímọ́ wà ní inú un rẹ.”

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 4