Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 3:9-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Wọ́n sọ fún ọba Nebukadinṣárì pé, “Kí ọba kí ó pẹ́.

10. Ìwọ ọba ti pàṣẹ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin gbọdọ̀ wólẹ̀ kí ó fi orí balẹ̀ fún ère wúrà

11. àti ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kí ó forí balẹ̀, a ó sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sínú iná ìléru.

12. Ṣùgbọ́n àwọn ará a Júdà kan wà, àwọn tí a yàn láti ṣe olórí agèégbè ìjọba Bábílónì: Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò, wọ́n ò ka ìwọ ọba sí. Wọn kò sin òrìṣà rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”

13. Nígbà náà ni Nebukadinéṣárì pàṣẹ ní ìrunú àti ìbínú pé kí a mú Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò wá, wọ́n sì mú wọn wá síwájú ọba.

14. Nebukadinéṣárì wí fún wọn wí pé, “Ṣé òtítọ́ ni, Sádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò wí pé ẹ̀yin kò sin òrìṣà mi àti pé ẹ̀yin kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí èmi gbé kalẹ̀.

15. Ní ìsinsìnyìí, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókun, ìpè àti onírúurú orin, bí ẹ̀yin bá ṣetan láti wólẹ̀ kí ẹ̀yin fi orí balẹ̀ fún ère tí mo gbé kalẹ̀ ó dára. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yìn bá kọ̀ láti sìn ín, lójúkan náà ni a ó gbé e yín jù sínú iná ìléru. Ǹjẹ́, ta ni Ọlọ́run náà tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi?”

16. Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò dá ọba lóhùn wí pé, “Nebukadinéṣárì, kì í ṣe fún wa láti gba ara wa sílẹ̀ níwájú u rẹ nítorí ọ̀rọ̀ yìí.

17. Bí ẹ̀yin bá jù wá sínú iná ìléru, Ọlọ́run tí àwa ń sìn lágbára láti gbà wá kúrò nínú un rẹ̀, yóò sì gbà wá lọ́wọ́ ọ̀ rẹ, ìwọ ọba.

18. Ṣùgbọ́n tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, a fẹ́ kí ìwọ ọba mọ̀ dájú wí pé àwa kò ní sin òrìṣà rẹ bẹ́ẹ̀ ni a kò ní fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”

19. Nígbà náà ni Nebukadinéṣárì bínú gidigidi sí Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò, ojú u rẹ̀ sì yípadà, ó sì pàṣẹ pé, kí wọn dá iná ìléru náà kí ó gbóná ní ìlọ́po méje ju èyí tí wọn ń dá tẹ́lẹ̀,

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 3