Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 3:14-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nebukadinéṣárì wí fún wọn wí pé, “Ṣé òtítọ́ ni, Sádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò wí pé ẹ̀yin kò sin òrìṣà mi àti pé ẹ̀yin kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí èmi gbé kalẹ̀.

15. Ní ìsinsìnyìí, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókun, ìpè àti onírúurú orin, bí ẹ̀yin bá ṣetan láti wólẹ̀ kí ẹ̀yin fi orí balẹ̀ fún ère tí mo gbé kalẹ̀ ó dára. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yìn bá kọ̀ láti sìn ín, lójúkan náà ni a ó gbé e yín jù sínú iná ìléru. Ǹjẹ́, ta ni Ọlọ́run náà tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi?”

16. Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò dá ọba lóhùn wí pé, “Nebukadinéṣárì, kì í ṣe fún wa láti gba ara wa sílẹ̀ níwájú u rẹ nítorí ọ̀rọ̀ yìí.

17. Bí ẹ̀yin bá jù wá sínú iná ìléru, Ọlọ́run tí àwa ń sìn lágbára láti gbà wá kúrò nínú un rẹ̀, yóò sì gbà wá lọ́wọ́ ọ̀ rẹ, ìwọ ọba.

18. Ṣùgbọ́n tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, a fẹ́ kí ìwọ ọba mọ̀ dájú wí pé àwa kò ní sin òrìṣà rẹ bẹ́ẹ̀ ni a kò ní fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”

19. Nígbà náà ni Nebukadinéṣárì bínú gidigidi sí Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò, ojú u rẹ̀ sì yípadà, ó sì pàṣẹ pé, kí wọn dá iná ìléru náà kí ó gbóná ní ìlọ́po méje ju èyí tí wọn ń dá tẹ́lẹ̀,

20. ó sì pàṣẹ fún àwọn alágbára nínú ogun rẹ̀ pé, kí wọ́n de Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò, kí wọn sì jù wọ́n sínú iná ìléru.

21. Nígbà náà ni a dè wọ́n pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn, ṣòkòtò, ìbòrí àti àwọn aṣọ mìíràn, a sì jù wọ́n sínú iná ìléru.

22. Nítorí bí àsẹ ọba ṣe le tó, tí iná ìléru náà sì gbóná, ọwọ́ iná pa àwọn ọmọ ogun tí wọ́n mú Sádírákì, Mésákì àti Àbẹ́dinígò lọ.

23. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò ṣubú lulẹ̀ sínú iná ìléru náà pẹ̀lú bí a ṣe dè wọ́n.

24. Nígbà náà ni ó ya Nebukadinéṣárì ọba lẹ́nu, ó sì yára dìde dúró, ó bèèrè lọ́wọ́ àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ pé, “Ṣe bí àwọn mẹ́ta ni a gbé jù sínú iná?”Wọ́n wí pé, “Òtítọ́ ni ọba.”

25. Ó sì wí pé, “Wò ó! Mo rí àwọn mẹ́rin tí a kò dè tí wọ́n ń rìn ká nínú iná, ẹnì kẹrin dàbí ọmọ Ọlọ́run.”

26. Nígbà náà, ni Nebukadinésárì dé ẹnu ọ̀nà iná ìléru, ó sì kígbe pé, “Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò, ìránṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀gá ògo, ẹ jáde, ẹ wá níbi!”Nígbà náà ni Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò jáde láti inú iná.

27. Àwọn ọmọ aládé, ìjòyè, baálẹ̀, àwọn ìgbìmọ̀ ọba pé jọ sí ọ̀dọ̀ ọ wọn. Wọ́n rí i wí pé iná kò ní agbára lára wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò jó wọn lára, bẹ́ẹ̀ ni irun orí i wọn kò jóná, àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn kò jóná, òórùn iná kò rùn ní ara wọn rárá.

28. Nígbà náà, ni Nebukadinésárì sọ wí pé, “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò, ẹni tí ó rán ańgẹ́lì rẹ̀ láti gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, wọn kọ àsẹ ọba, dípò èyí, wọ́n fi ara wọn lélẹ̀ ju kí wọn sìn tàbí forí balẹ̀ fún Ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọ́run wọn.

29. Nítorí náà, mo pa àṣẹ pé, ẹnikẹ́ni, orílẹ̀ èdè tàbí èdè kan tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò kí a gé wọn sí wẹ́wẹ́ kí a sì sọ ilé e wọn di ààtàn; nítorí kò sí Ọlọ́run mìíràn tí ó lè gba ènìyàn bí irú èyí.”

30. Nígbà náà ni ọba gbé Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dinígò ga ní gbogbo agbégbé ìjọba Bábílónì.

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 3