Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 11:22-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Nígbà náà, ni a ó gbà ogunlọ́gọ̀ ogun kúrò níwájú u rẹ̀, pẹ̀lú òun àti ọmọ aládé ti májẹ̀mu náà ni a ó parun.

23. Lẹ́yìn tí ó wá ṣe ìpinnu pẹ̀lú u rẹ̀, yóò hùwà ẹ̀tàn, pẹ̀lú iwọ̀nba ènìyàn kékeré ni yóò gba ìjọba.

24. Nígbà tí àwọn agbègbè tí ó lọ́rọ̀ gidigidi wà láìbẹ̀rù ni yóò gbógun tì wọ́n, yóò ṣe ohun tí baba rẹ̀ tàbí baba ńlá rẹ̀ kò ṣe rí, yóò pín ìkógún ẹrù àti ọrọ̀ fún àwọn ọmọ lẹ́yìn in rẹ̀. Yóò pète àti bi àwọn ìlú olódi ṣubú, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀ ni.

25. “Pẹ̀lú ogun púpọ̀, yóò sì ru agbára rẹ̀ àti ìgboyà rẹ̀ ṣókè sí ọba Gúṣù. Ọba Gúṣù yóò dìde ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun tí ó lágbára gidigidi, ṣùgbọ́n kò ní leè dúró, nítorí ọ̀tẹ̀ tí ó gbérò sí i.

26. Àwọn tí ó jẹ nínú oúnjẹ ọba yóò gbìyànjú láti parun: a ó gbá ogun rẹ̀ dànú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò ṣubú sí ogun.

27. Àwọn ọba méjèèjì, ọkàn wọn tẹ̀ sí búburú, wọn yóò jókòó lórí tábìlì kan, wọn yóò máa parọ́ sí ara wọn, ṣùgbọ́n kò ní yọrí sí nǹkan kan nítorí òpin yóò wá ní àsìkò tí a yàn.

28. Ọba àríwá yóò padà sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ yóò lòdì sí májẹ̀mú mímọ́, yóò sì ṣiṣẹ́ lòdì sí i, yóò sì padà sí orílẹ̀-èdè oun fúnra rẹ̀.

29. “Ní àsìkò tí a yàn, yóò gbógun sí Gúṣù lẹ́ẹ̀ kan sí i, ṣùgbọ́n ní ìgbà yí àyọrísí yóò yàtọ̀ sí ti ìṣáájú.

30. Nítorí pé, ọkọ̀ ojú omi àwọn ilẹ̀ etídò ìwọ̀-oòrùn yóò ta kòó, ọkàn rẹ̀ yóò sì pámi. Nígbà náà, ni yóò padà, yóò sì bínú sí májẹ̀mu mímọ́, yóò sì padà, yóò sì fi ojú rere hàn sí àwọn tí ó kọ májẹ̀mu mímọ́ náà.

31. “Agbára ọmọ ogun rẹ̀ yóò dìde láti ba ohun mímọ́ ilé olódi tẹ́ḿpìlì jẹ́, yóò sì pa ẹbọ ojoojúmọ́ rẹ́. Nígbà náà ni wọn yóò gbé ìríra tí ó fa ìsọdahoro kalẹ̀.

32. Pẹ̀lú ẹ̀tàn ni yóò bá àwọn tí ó ba májẹ̀mú jẹ́, ṣùgbọ́n, àwọn tí ó mọ Ọlọ́run wọn yóò jẹ́ alágbára. Wọn yóò sì kọjú ìjà sí i.

33. “Àwọn tí ó mòye yóò máa kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀, wọn yóò máa ṣubú nípa idà tàbí kí a jó wọn tàbí ìgbèkùn tàbí nípa ìkógún.

34. Nígbà tí wọ́n bá ṣubú, wọn yóò rí ìrànlọ́wọ́ díẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣe aláìsòótọ́ yóò sì dara pọ̀ mọ́ wọn.

35. Lára àwọn tí ó mòye yóò kọsẹ̀, nítorí kí a baà tún wọn ṣe, wọ́n di mímọ́ àti aláìlábàwọ́n títí di ìgbà ìkẹyìn nítorí yóò sì wá ní àkókò tí a yàn.

36. “Ọba yóò ṣe bí ó ti wù ú yóò sì gbé ara rẹ̀ ga, ju gbogbo òrìṣà lọ, yóò máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò-ṣe-é-gbọ́-létí sí Ọlọ́run àwọn Ọlọ́run, a yóò sì máa yege títí àkókò ìbínú yóò fi parí, nítorí ohun tí a ti pinnu yóò ṣẹlẹ̀.

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 11