Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 57:7-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ìwọ ti ṣe bẹ́ẹ̀dì rẹ lórí òkè gíga tí ó rẹwà;níbẹ̀ ni ẹ lọ láti lọ ṣe ìrúbọ yín.

8. Lẹ́yìn àwọn ìlẹ̀kùn yín àti òpó ìlẹ̀kùn yínníbẹ̀ ni ẹ fi àwọn àmì òrìṣà yín sí.Ní kíkọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sí bẹ́ẹ̀dì yín sílẹ̀,ẹ gun oríi rẹ̀ lọ, ẹ sì sí i sílẹ̀ gbagada;ẹ ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn bẹ́ẹ̀dì wọn,ẹ̀yin sì ń wo ìhòòhò wọn.

9. Ẹ̀yin lọ sí Mólẹ́kì pẹ̀lú òróró ólífìẹ sì fi kún òórùn dídùn yín.Ẹ rán ikọ̀ yín lọ jìnnà réré;ẹ sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú!

10. Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ baa yín,ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, ‘kò sí ìrètí mọ́?’Ẹ rí okun kún agbára yín,nípá bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ọ yín.

11. “Ta ni ó ń pá yín láyà tí ń bà yín lẹ́rùtí ẹ fi ń ṣèké sí mi,àti tí ẹ̀yin kò fi rántí mitàbí kí ẹ rò yí nínú ọkàn yín?Ǹjẹ́ kì í ṣe nítoríi dídákẹ jẹ́ ẹ́ mi fún ìgbà pípẹ́tí ẹ̀yin kò fi bẹ̀rù mi?

12. Èmi yóò sí òdodo yín payá àti iṣẹ́ẹ yín,wọn kì yóò sì ṣe yín ní àǹfààní.

13. Nígbà tí ẹ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́ẹ jẹ́ kí àkójọ àwọn ère yín gbà yín!Atẹ́gùn yóò gbá gbogbo wọn lọ,èémí lásán làsàn ni yóò gbá wọn lọ.Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi mí ṣe ààbò rẹ̀ni yóò jogún ilẹ̀ náàyóò sì jogún òkè mímọ́ mi.”

14. A ó sì sọ wí pé:“Tún mọ, tún mọ, tún ọ̀nà náà ṣe!Ẹ mú àwọn ohun ìkọ̀ṣẹ̀ kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.”

15. Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wíẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́:“Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́,ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀,láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jíàti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí.

16. Èmi kì yóò fẹ̀ṣùn kan ni títí láé,tàbí kí n máa bínú ṣá á,nítorí nígbà náà ni ọkàn ọmọnìyàn yóòrẹ̀wẹ̀sì níwájú mièémí ọmọnìyàn tí mo ti dá.

17. Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúà rẹ̀;mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojúù mi pamọ́ ní ìbínúṣíbẹ̀, ó tẹ̀ṣíwájú nínú tinú-mi-ni-n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀.

18. Èmi ti rí ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ṣùgbọ́n Èmi yóò wò ó sàn;Èmi yóò tọ́ ọ sọ́nà n ó sì mú ìtùnú tọ̀ ọ́ wá,

Ka pipe ipin Àìsáyà 57