Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 57:4-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ta ni ó fi ń ṣẹlẹ́yà?Ta ni o ń yọ ṣùtì sítí o sì yọ ahọ́n síta?Ẹ̀yin kì í haá ṣe ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn bí,àti ìràn àwọn òpùrọ́?

5. Ẹ gbinájẹ fún ìṣekúṣe láàrin igi óákùàti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀;ẹ fi àwọn ọmọ yín rúbọ nínú kòtò jínjìnàti lábẹ́ àwọn pàlàpálá òkúta.

6. Àwọn ère tí ó wà ní àárin òkúta dídánwọ̀n n nì, nínú kòtò jínjìn ni ìpín in yín;àwọn, àwọ̀n ni ìpín in yín.Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀àti láti ta ọrẹ oníhóró.Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹkí n dáwọ́ dúró?

7. Ìwọ ti ṣe bẹ́ẹ̀dì rẹ lórí òkè gíga tí ó rẹwà;níbẹ̀ ni ẹ lọ láti lọ ṣe ìrúbọ yín.

8. Lẹ́yìn àwọn ìlẹ̀kùn yín àti òpó ìlẹ̀kùn yínníbẹ̀ ni ẹ fi àwọn àmì òrìṣà yín sí.Ní kíkọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sí bẹ́ẹ̀dì yín sílẹ̀,ẹ gun oríi rẹ̀ lọ, ẹ sì sí i sílẹ̀ gbagada;ẹ ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn bẹ́ẹ̀dì wọn,ẹ̀yin sì ń wo ìhòòhò wọn.

9. Ẹ̀yin lọ sí Mólẹ́kì pẹ̀lú òróró ólífìẹ sì fi kún òórùn dídùn yín.Ẹ rán ikọ̀ yín lọ jìnnà réré;ẹ sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú!

10. Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ baa yín,ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, ‘kò sí ìrètí mọ́?’Ẹ rí okun kún agbára yín,nípá bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ọ yín.

11. “Ta ni ó ń pá yín láyà tí ń bà yín lẹ́rùtí ẹ fi ń ṣèké sí mi,àti tí ẹ̀yin kò fi rántí mitàbí kí ẹ rò yí nínú ọkàn yín?Ǹjẹ́ kì í ṣe nítoríi dídákẹ jẹ́ ẹ́ mi fún ìgbà pípẹ́tí ẹ̀yin kò fi bẹ̀rù mi?

Ka pipe ipin Àìsáyà 57