Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 57:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olódodo ṣègbékò sí ẹnìkan tí ó rò ó lọ́kàn ara rẹ̀;a mú àwọn ẹni mímọ́ lọ,kò sì sí ẹni tó yépé a ti mú àwọn olódodo lọláti yọ wọ́n kúrò nínú ibi.

2. Gbogbo àwọn tí ń rìn déédééń wọ inú àlàáfíà;wọ́n rí ìsinmi bí wọ́n ti ń sùn lókùú.

3. “Ṣùgbọ́n ìwọ wá níhìnín, ìwọ ọmọ àjẹ́ yìí,ìwọ ìran panṣágà àti aṣẹ́wó!

4. Ta ni ó fi ń ṣẹlẹ́yà?Ta ni o ń yọ ṣùtì sítí o sì yọ ahọ́n síta?Ẹ̀yin kì í haá ṣe ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn bí,àti ìràn àwọn òpùrọ́?

5. Ẹ gbinájẹ fún ìṣekúṣe láàrin igi óákùàti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀;ẹ fi àwọn ọmọ yín rúbọ nínú kòtò jínjìnàti lábẹ́ àwọn pàlàpálá òkúta.

6. Àwọn ère tí ó wà ní àárin òkúta dídánwọ̀n n nì, nínú kòtò jínjìn ni ìpín in yín;àwọn, àwọ̀n ni ìpín in yín.Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀àti láti ta ọrẹ oníhóró.Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹkí n dáwọ́ dúró?

7. Ìwọ ti ṣe bẹ́ẹ̀dì rẹ lórí òkè gíga tí ó rẹwà;níbẹ̀ ni ẹ lọ láti lọ ṣe ìrúbọ yín.

8. Lẹ́yìn àwọn ìlẹ̀kùn yín àti òpó ìlẹ̀kùn yínníbẹ̀ ni ẹ fi àwọn àmì òrìṣà yín sí.Ní kíkọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sí bẹ́ẹ̀dì yín sílẹ̀,ẹ gun oríi rẹ̀ lọ, ẹ sì sí i sílẹ̀ gbagada;ẹ ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn bẹ́ẹ̀dì wọn,ẹ̀yin sì ń wo ìhòòhò wọn.

9. Ẹ̀yin lọ sí Mólẹ́kì pẹ̀lú òróró ólífìẹ sì fi kún òórùn dídùn yín.Ẹ rán ikọ̀ yín lọ jìnnà réré;ẹ sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú!

10. Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ baa yín,ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, ‘kò sí ìrètí mọ́?’Ẹ rí okun kún agbára yín,nípá bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ọ yín.

Ka pipe ipin Àìsáyà 57