Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 37:6-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Àìṣáyà sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé, ‘Ohun tí Olúwa sọ nìyìí: Má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba Ásíríà tí ó wà nínú ìdè ti fi sọ̀rọ̀ òdì sí mi.

7. Tẹ́tísílẹ̀! Èmi yóò fi ẹ̀mí kan sínú rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bí o bá ti gbọ́ ìròyìn kan, òun yóò padà sí orílẹ̀ èdè rẹ̀, níbẹ̀ ni n ó sì ti jẹ́ kí wọn ké e lulẹ̀ pẹ̀lú idà.’ ”

8. Nígbà tí ọ̀gágun gbọ́ pé ọba Áṣíríà ti fi Lákísì sílẹ̀, ó padà sẹ́yìn, ó sì bá ọba tí ń bá Líbínà jà.

9. Ní àkókò yìí Ṣenakérúbù gbọ́ ìròyìn kan pé Tíhákà ará Kúṣì ọba Éjíbítì ń jáde bọ̀ wá bá òun jà. Nígbà tí ó gbọ́ èyí, ó rán oníṣẹ́ sí Heṣekáyà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí:

10. “Ẹ sọ fún Heṣekáyà ọba Júdà pé: Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tàn ọ́ jẹ nígbà tí ó sọ pé, ‘a kì yóò jọ̀wọ́ Jérúsálẹ́mù fún ọba Ásíríà.’

11. Dájúdájú, ìwọ ti gbọ́ ohun tí ọba Ásíríà ti ṣe sí àwọn orílẹ̀ èdè, tí ó pa wọ́n run pátapáta. Ǹjẹ́ a ó ha dá ọ nídè bí?

12. Ǹjẹ́ àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀ èdè tí àwọn baba ńlá mi parun ha gbà wọ́n sílẹ̀ bí àwọn òrìṣà Gósénì, Háránì, Résípì àti àwọn ènìyàn Ẹ́dẹ́nì tí wọ́n wà ní ìlú Áṣárì?

13. Níbo ni ọba Hámátì wà, ọba Ápádì, ọba Ìlú Ṣefáfíámù tàbí Hénà tàbí Ífà?”

14. Heṣekáyà gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ ó sì kà á. Lẹ́yìn náà ni ó gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlì Olúwa ó sì tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú Olúwa.

15. Heṣekáyà sì gbàdúrà sí Olúwa:

16. Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó gúnwà láàrin àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lóríi gbogbo ìjọba orílẹ̀ ayé. Ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé.

17. Tẹ́tí sílẹ̀, Ìwọ Olúwa, kí o gbọ́, ya ojú rẹ, Ìwọ Olúwa, kí o rí i; tẹ́tí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ṣenakérúbù rán láti fi àbùkù kan Ọlọ́run alààyè.

18. “Òtítọ́ ni ìwọ Olúwa pé àwọn ọba Ásíríà ti sọ àwọn ènìyàn àti ilẹ̀ wọn di asán.

19. Wọ́n ti da àwọn òrìṣà wọn sínú iná wọ́n sì ti pa wọ́n run, nítorí àwọn wọ̀nyí kì í ṣe ọlọ́run bí kò ṣe igi àti òkúta lásán, tí a ti ọwọ́ ènìyàn ṣe.

20. Nísinsìn yìí, Ìwọ Olúwa, Ọlọ́run wa, gbà wá lọ́wọ́ọ rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé yóò fi mọ̀ pé Ìwọ, Ìwọ nìkan, Olúwa ni Ọlọ́run.”

21. Lẹ́yìn náà Àìṣáyà ọmọ Ámósì rán iṣẹ́ kan sí Heṣekáyà: “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ pé: Nítorí pé ìwọ ti gbàdúrà sí mi nípa Ṣenakérúbù ọba Áṣíríà,

22. èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀:“Wúndíá ọmọbìnrin Ṣíhónìkẹ́gàn ó sì fi ọ ṣe yẹ̀yẹ́.Ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mùmi oríi rẹ̀ bí ó ti ń sálọ.

23. Ta ni ìwọ ti bú tí ìwọ sì ti sọ̀rọ̀ òdì sí?Sí ta ní ìwọ ti gbé ohùn rẹ sókètí o sì gbé ojú rẹ sókè ní ìgbéraga?Sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì!

24. Nípa àwọn oníṣẹ́ rẹìwọ ti mú àbùkù bá Olúwa.Ìwọ sì ti sọ wí pé‘pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin miÈmi ti gun orí òkè ńlá ńlá,ibi gíga jùlọ ti Lébánónì.Èmi ti gé igi kédárì rẹ tí ó ga jùlọ lulẹ̀,àti àyànfẹ́ igi páínì.Èmi ti dé ibi rẹ̀ tí ó ga jùlọ,igbó rẹ̀ tí ó dára jùlọ.

Ka pipe ipin Àìsáyà 37