Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 33:12-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. A ó jó àwọn ènìyàn run bí eérú;bí igbó ẹ̀gún tí a gé la ó dáná sí wọn.”

13. Ìwọ tí ó wà lọ́nà jínjìn, gbọ́ ohuntí mo ti ṣe;Ìwọ tí ò ń bẹ nítòsí, jẹ́rìí agbára mi!

14. Èrù ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní Ṣíhónì;ìwárìrì bá àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́:“Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná ajónirun?Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú ìjóná àìnípẹ̀kun?”

15. Ẹni tí ó ń rìn lódodotí ó ń sọ ohun tí ó tọ́,tí ó kọ èrè tí ó tibi ìlọ́nilọ́wọ́gbà wá,tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,tí ó di etíi rẹ̀ sí ọ̀tẹ̀ láti pànìyàntí ó sì di ojúu rẹ̀ sí àtipète ibi

16. ọkùnrin náà nìyìí tí yóò gbé ní ibi gíga,ẹni tí ààbò rẹ̀ yóò jẹ́ òkè ńlá olódi.A ó máa mú àkàrà rẹ̀ wábẹ́ẹ̀ ni omi kì yóò wọ́n ọn.

17. Ojúu rẹ yóò rí ọba nínú ẹwà rẹ̀yóò sì rí ilẹ̀ kan tí ó tẹ́ lọ rẹrẹẹrẹ.

18. Nínú èrò rẹ ìwọ yóò rántí ẹ̀rù rẹ àtẹ̀yìnwá:“Níbo ni ọ̀gá àgbà náà wà?Níbo ni ẹni tí ń gba owó òde wà?Níbo ni òṣìṣẹ́ ti ó ń mójú tó ilé-ìṣọ́ wà?”

19. Ìwọ kì yóò rí àwọn agbéraga ènìyàn wọ̀nyẹn mọ́,àwọn ènìyàn tí èdè wọn farasin,pẹ̀lú ahọ́n tí ó ṣàjèjì tí kò sì yéni.

20. Gbójú ṣókè sí Ṣíhónì, ìlú àjọ̀dún wa,ojú rẹ yóò rí Jérúsálẹ́mù,ibùgbé àlàáfíà nnì, àgọ́ tí a kò ní yí padà;àwọn òpó rẹ̀ ni a kì yóò fàtutàbí èyíkéyìí nínú okùn rẹ̀ kí já.

Ka pipe ipin Àìsáyà 33