Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 30:19-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ẹ̀yin ènìyàn Ṣíhónì, tí ń gbé ní Jérúsálẹ́mù, ìwọ kì yóò ṣunkún mọ́. Báwo ni àánú rẹ̀ yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́! Bí ó bá ti gbọ́, òun yóò dá ọ lóhùn.

20. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fún ọ ní àkàrà ìyà àti omi ìpọ́njú, àwọn olùkọ́ rẹ kì yóò farasin mọ́; pẹ̀lú ojú rẹ ni ìwọ ó rí wọn.

21. Bí o bá yí sápá ọ̀tún tàbí apá òsi, etí rẹ yóò máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn rẹ, wí pé, “Ọ̀nà nìyìí, máa rìn nínú rẹ̀.”

22. Lẹ́yìn náà ni ẹ ó ba àwọn ère yín jẹ́ àwọn tí ẹ fi fàdákà bò àti àwọn ère tí ẹ fi wúrà bò pẹ̀lú, ẹ ó sọ wọ́n nù bí aṣọ tí obìnrin fi ṣe nǹkan oṣù ẹ ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kúrò níbí!”

23. Òun yóò sì rọ òjò fún un yín sí àwọn irúgbìn tí ẹ gbìn sórí ilẹ̀, oúnjẹ tí yóò ti ilẹ̀ náà wá yóò ní ọ̀rá yóò sì pọ̀. Ní ọjọ́ náà ni àwọn ẹran ọ̀sìn yín yóò máa jẹ koríko ní pápá oko tútù tí ó tẹ́jú.

24. Àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ń tú ilẹ̀ yóò jẹ oúnjẹ àdídùn tí a fi amúga àti ṣọ́bìrì fọ́nkálẹ̀.

25. Ní ọjọ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò sọ ẹ̀míi wọn nù nígbà tí ilé ìṣọ́ yóò wó lulẹ̀, odò omi yóò ṣàn lórí òkè gíga àti lórí àwọn òkè kékeré.

26. Òṣùpá yóò sì tàn bí òòrùn, àti ìtànsán òòrùn yóò mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po méje, gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ odidi ọjọ́ méje, nígbà tí Olúwa yóò di ojú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí yóò sì wo ọgbẹ́ tí ó ti dá sí wọn lára sàn.

27. Kíyèsí i, orúkọ Olúwa ti òkèèrè wápẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti kùrukùruèéfín tí ó nípọn;ètè rẹ̀ kún fún ìbínúahọ́n rẹ̀ sì jẹ́ iná ajónirun.

28. Èémíi rẹ̀ sì dàbí òjò alágbára,tí ó rú sókè dé ọ̀run.Ó jọ àwọn orílẹ̀ èdè nínú asẹ́ ìparun;ó sì fi sí àgbọ̀n àwọn ènìyànkókó kan tí ó ń sì wọ́n lọ́nà.

29. Ẹ̀yin ó sì kọringẹ́gẹ́ bí i ti alẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe àjọyọ̀ àpéjọ mímọ́,ọkàn yín yóò yọ̀gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn ènìyàn gòkè lọ pẹ̀lúu fèrèsí orí òkè Olúwa,àní sí àpáta Ísírẹ́lì.

30. Olúwa yóò jẹ́ kí wọn ó gbọ́ ohùn ògo rẹ̀yóò sì jẹ́ kí wọ́n rí apá rẹ̀ tí ó ń bọ̀ wálẹ̀pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti iná ajónirun,pẹ̀lúu mọ̀nàmọ́ná, àrá àti yìnyín.

31. Ohùn Olúwa yóò fọ́ Áṣíríà túútúú,pẹ̀lú ọ̀pá aládé rẹ̀ ni yóò lù wọ́n bolẹ̀.

32. Ẹgba kọ̀ọ̀kan tí Olúwa bá gbé lé wọnpẹ̀lú ọ̀pá ìjẹníyà rẹ̀yóò jẹ́ ti ìlù tamborínì àti ti hápù,gẹ́gẹ́ bí ó ti ń bá wọn jà lójú ogunpẹ̀lú ẹ̀sẹ́ láti apá rẹ̀.

33. A ti tọ́jú Tófẹ́tì sílẹ̀ tipẹ́tipẹ́,a ti tọ́jú rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba.Ojú ààrò rẹ̀ ni a ti gbẹ́ jìn tí ó sì fẹ̀,pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ iná àti igi ìdáná;èémí Olúwa,gẹ́gẹ́ bí ìsàn ṣúfúrù tí ń jó ṣe mú un gbiná.

Ka pipe ipin Àìsáyà 30