orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ábúsálómù Dìtẹ̀ Sí Dáfídì Baba Rẹ̀.

1. Lẹ́yin èyí náà, Ábúsálómù sì pèṣè kẹ̀kẹ́ àti ẹsin fún ara rẹ̀, àti àádọ́ta ọmọkùnrin tí yóò máa sáré níwájú rẹ̀.

2. Ábúsálómù sì dìde ní kùtùkùtù, ó sì dúró ní apákan ọ̀nà ẹnu ibodé: bí ẹnìkan bá ní ẹjọ́ tí ó ń fẹ́ mú tọ ọba wá fún ìdájọ́, a sì pè é sọ́dọ̀ rẹ̀, a sì bi í pé, “Ará ìlú wo ni ìwọ?” Òun a sì dáhùn pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ti inú ọ̀kan nínú ẹ̀yà Ísírẹ́lì wá.”

3. Ábúsálómù yóò sì wí fún un pé, “Wò ó, ọ̀ràn rẹ sá dára, ó sì tọ́: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ọba fi àṣẹ fún láti gbọ́ ọ̀ràn rẹ.”

4. Ábúsálómù a sì wí pé, “À bá jẹ́ fi mi ṣe onídájọ́ ní ilẹ̀ yìí! Kí olúkúlùkù ẹni tí ó ní ẹjọ́ tàbí ọ̀ràn kan báà lè máa tọ̀ mí wá, èmi ìbá sì ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún un.”

5. Bẹ́ẹ̀ ni bí ẹnìkan bá sì súnmọ́ ọn láti tẹ́ribá fún un, òun a sì nawọ́ rẹ̀, a sì dì í mú, a sì fí ẹnu kò ó lẹ́nú.

6. Irú ìwà bàyìí ni Ábúsálómù sì fi fa ọkàn àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì sọ́dọ̀ rẹ̀.

7. Ó sì ṣe lẹ́yìn ogójì ọdún, Ábúsálómù sì wí fún ọba pé, “Èmi bẹ́ ọ́, jẹ́ kí èmi ó lọ, kí èmi sì san ìlérí mi tí èmi ti ṣe fún Olúwa, ní Hébírónì.

8. Nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ti jẹ́jẹ̀ẹ́ kan nígbà tí èmi ń bẹ ní Géṣúrì ní Síríà pé, ‘Bí Olúwa bá mú mi padà wá sí Jérúsálẹ́mù, nítòótọ́, èmi ó sì sin Olúwa.’ ”

9. Ọba sì wí fún un pé, “Má a lọ ní àlàáfíà.” Ó sì dìde, ó sì lọ sí Hébúrónì.

10. Ṣùgbọ́n Ábúsálómù rán àmì sáàrin gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá gbọ́ ìró ìpè, kí ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ábúsálómù jọba ní Hébúrónì.’ ”

11. Igba ọkùnrin sì bá Ábúsálómù ti Jérúsálẹ́mù jáde, nínú àwọn tí a ti pè; wọ́n sì lọ nínú àìmọ̀kan wọn, wọn kò sì mọ nǹkankan.

12. Ábúsálómù sì ránṣẹ́ pe Áhítófélì ará Gílónì, ìgbìmọ̀ Dáfídì, láti ìlú rẹ̀ wá, àní láti Gílónì, nígbà tí ó ń rú ẹbọ. Ìdìmọ̀lù náà sì le; àwọn ènìyàn sì ń pọ̀ sọ́dọ̀ Ábúsálómù.

Dáfídì Sá Lọ Kúrò Lórí Oyè.

13. Ẹnìkan sì wá rò fún Dáfídì pé, “Ọkàn àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ṣí sí Ábúsálómù.”

14. Dáfídì sì wí fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wá lọ́dọ̀ rẹ̀ ni Jérúsálẹ́mù pé, “Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a sá lọ, nítorí pé kò sí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ Ábúsálómù; ẹ yára, kí a lọ kúrò, kí òun má báà yára lé wa bá, kí ó má sì mú ibi bá wa, kí ó má sì fi ojú idà pa ìlú run.”

15. Àwọn ìránṣẹ́ ọba sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Olúwa wa ọba ń fẹ́, wò ó, àwa ìránṣẹ rẹ̀ ti murá.”

16. Ọba sì jáde, gbogbo ilé rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Ọba sì fì mẹ́wàá nínú àwọn obìnrin rẹ̀ sílẹ̀ láti máa sọ́ ilé.

17. Ọba sì jáde, gbogbo ènìyàn sì tẹ̀lé e, wọ́n sì dúró ní ibìkan tí ó jìnnà.

18. Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì kọjá sí ìwájú rẹ̀, àti gbogbo àwọn Kérétì, àti gbogbo àwọn Pélétì, àti gbogbo àwọn ará Gítì, ẹgbẹ̀ta ọmọkùnrin tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Gátì wá, sì kọjá níwájú ọba.

Ìwà Òótọ́ Ítaì Ará Gítì.

19. Ọba sì wí fún Ítaì, ará Gítì pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń bá wa lọ pẹ̀lú, padà, kí o sì ba ọba jókòó; nítorí pé aléjò ni ìwọ, ìwọ sì ti fi ìlú rẹ sílẹ̀.

20. Lánàá yìí ni ìwọ dé, èmi ó ha sì mú kí ìwọ máa bá wá lọ kákiri lónìí bí? Èmi ń lọ sí ibikíbi tí mo bá rí: padà, kí o sì mú àwọn arakùnrin rẹ padà, kí àánú àti òtítọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”

21. Ítaì sì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé, “Bí Olúwa tí ń bẹ láàyè, àti bí Olúwa mi ọba ti ń bẹ láàyè, nítòótọ́ níbikíbi tí Olúwa mi ọba bá gbé wà, ìbáà ṣe nínú ikú, tàbí nínú ìyè, níbẹ̀ pẹ̀lú ni ìránṣẹ́ rẹ yóò gbé wà.”

22. Dáfídì sì wí fún Ítaì pé, “Lọ kí o sì rékọjá!” Ítaì ará Gítì náà sì rékọjá, àti gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn ọmọ kékèké tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀.

23. Gbogbo ìlú náà sì fi ohùn rara sunkún, gbogbo ènìyàn sì rékọjá; ọba sì rékọjá odò Kídírónì, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì rékọjá, sí ìhà ọ̀nà ijù.

A Gbé Àpótí-ẹ̀rí Padà Sí Ìlú Jérúsálẹ́mù.

24. Sì wò ó, Sádókù pẹ̀lú àti gbogbo àwọn ọmọ Léfì tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ń ru àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run: wọ́n sì gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run náà sọ̀kalẹ̀; Ábíátarì sí gòkè, títí gbogbo àwọn ènìyàn sì fi dẹ́kun àti máa kọjá láti ìlú wá.

25. Ọba sì wí fún Sádókù pé, “Sì tún gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run náà padà sí ìlú: bí èmi bá rí ojú rere gbà lọ́dọ̀ Olúwa, yóò sì tún mú mi padà wá, yóò sì fi àpótí-ẹ̀rí náà hàn mí àti ibùgbé rẹ̀.

26. Ṣùgbọ́n bí òun bá sì wí pé, ‘Èmi kò ní inú dídùn sí ọ,’ wò ó, èmi nì yìí, jẹ́ kí òun ó ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti tọ́ ní ojú rẹ̀.”

27. Ọba sì wí fún Sádókù àlùfáà pé, “Aríran ha kọ́ ni ọ́? Padà sí ìlú ní àlàáfíà, àti àwọn ọmọ rẹ méjèèjì pẹ̀lú rẹ, Áhímásì ọmọ rẹ, àti Jónátanì ọmọ Ábíátárì.

28. Wò ó, èmi ó dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ijù náà, títí ọ̀rọ̀ ó fi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá láti sọ fún mi.”

29. Sádókù àti Ábíátarì sì gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run padà sí Jérúsálẹ́mù: wọ́n sì gbé ibẹ̀.

Áhítófélì Lọ́wọ́ Sí Ìdìtẹ̀ Náà.

30. Dáfídì sì ń gòkè lọ ní òkè igi ólífì, o sì ń sunkun bí ó ti ń gòkè lọ, ó sì bo orí rẹ̀, ó ń lọ láìní bàtà ní ẹṣẹ̀: gbogbo ènìyàn tí o wà lọ́dọ̀ rẹ̀, olúkúlùkù ọkùnrin sì bo orí rẹ̀, wọ́n sì ń gòkè lọ, wọ́n ń sunkún bí wọ́n ti ń gòkè lọ.

31. Ẹnìkan sì sọ fún Dáfídì pé, “Áhítófélì wà nínú àwọn asọ̀tẹ̀ pẹ̀lù Ábúsálómù.” Dáfídì sì wí pé, “Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, sọ ìmọ̀ Áhítófélì di asán.”

Húsáì Padà Sí Jérúsálẹ́mù.

32. Ó sì ṣe, Dáfídì dé orí òkè, níbi tí ó gbé wólẹ̀ sin Ọlọ́run, sì wò ó, Húsáì ará Áríkà sì wá láti pàdé rẹ̀ pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ yíya, àti erùpẹ̀, lórí rẹ̀.

33. Dáfídì sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá bá mi kọjá, ìwọ ó sì jẹ́ ìdíwọ́ fún mi.

34. Bí ìwọ bá sì padà sí ìlú, tí o sì wí fún Ábúsálómù pé, ‘Èmi ó ṣe ìránṣẹ́ rẹ ọba, gẹ́gẹ́ bí èmi ti ṣe ìránṣẹ́ baba rẹ nígbà àtíjọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó sì jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ nísínsinyìí,’ kí ìwọ sì bá ìmọ̀ Áhítófélì jẹ́.

35. Ṣé Sádókù àti Ábíátarì àwọn àlùfáà wà níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀? Yóò sì ṣe, ohunkóhùn tí ìwọ bá gbọ́ láti ilé ọba wá, ìwọ ó sì sọ fún Sádókù àti Ábíátarì àwọn àlùfáà.

36. Wò ó, àwọn ọmọ wọn méjèèjì sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú wọn, Áhímásì ọmọ Sádókù, àti Jónátánì ọmọ Ábíátárì; láti ọwọ́ wọn ni ẹ̀yín ó sì rán ohùnkóhun tí ẹ̀yín bá gbọ́ sí mi.”

37. Húsáì ọ̀rẹ́ Dáfídì sì wá sí ìlú, Ábúsálómù sì wá sí Jérúsálẹ́mù.