orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

A Dójúti Àwọn Ìránṣẹ́ Dáfídì Ní Ilé Ámónì.

1. Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, ọba àwọn ọmọ Ámónì sì kú, Hánúnì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

2. Dáfídì sì wí pé, “Èmi yóò ṣe ooré fún Hánúnì ọmọ Náhásì gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ sì ti ṣe oore fún mi.” Dáfídì sì ìránṣẹ́ láti tù ú nínú láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wá, nítorí ti baba rẹ̀.Àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì wá sí ilé àwọn ọmọ Ámónì.

3. Àwọn olórí àwọn ọmọ Ámónì sì wí fún Hánúnì Olúwa wọn pé, “Ǹjẹ́ o rò pé Dáfídì ń bu ọlá fún baba rẹ nígbà tí ó rán ènìyàn wá láti bá ọ kẹ́dùn? Kò ha ṣe pé Dáfídì rán àwọn ìránṣẹ́ sí ọ láti wo ìlú àti láti yọ́ ọ wò àti láti gbà ọ́.”

4. Hánúnì sì mú àwọn ìránṣẹ Dáfídì ó fá apákan irungbọ̀n wọn, ó sì gé ààbọ̀ kúró ní agbádá wọn, títí ó fí dé ìdí wọn, ó sì rán wọn lọ.

5. Wọ́n sì sọ fún Dáfídì, ó sì ránṣẹ́ lọ pàdé wọn, nítorí tí ojú ti àwọn ọkùnrin náà púpọ̀: ọba sì wí pé, “Ẹ dúró ní Jẹ́ríkò títí irungbọ̀n yín yóò fi hù, nígbà náà ni kí ẹ tó máa bọ̀.”

Àwọn Ogun Síríà àti Ámónì Sá Níwájú Ísírẹ́lì.

6. Àwọn ọmọ Ámónì sì ri pé, wọ́n di ẹni ìríra níwájú Dáfídì, àwọn ọmọ Ámónì sì ránṣẹ, wọ́n sì fi owó bẹ́ ogún àwọn ará Síríà ti Bẹtire-hóhù; àti Síríà ti Sóbà, ẹgbaàwá ẹlẹ́sẹ̀ àti ti ọba Máákà, ẹgbẹ̀run ọkùnrin àti ti Isítóbù ẹgbàafà ọkùnrin lọ́wẹ̀.

7. Dáfídì sì gbọ́, ó sì rán Jóábù, àti gbogbo ogún àwọn ọkùnrin alágbára.

8. Àwọn ọmọ Ámónì sì jáde, wọ́n sì tẹ́ ogún ní ẹnu odi; ará Síríà ti Sóbà, àti ti Réhóbù, àti Ísítóbù, àti Máákà, wọ́n sì tẹ ogun ni pápá fún ara wọn.

9. Nígbà tí Jóábù sì ríi pé ogun náà dojú kọ òun níwájú àti lẹ́yìn, ó sì yàn nínú gbogbo àwọn akíkanjú ọkùnrin ní Ísírẹ́lì, ó sì tẹ́ ogun kọjú sí àwọn ará Síríà.

10. Ó sì fi àwọn ènìyàn tí ó kù lé Ábíṣáì àbúrò rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè tẹ ogun kọjú sí àwọn ọmọ Ámónì.

11. Ó sì wí pé, “Bí agbára àwọn ará Síríà bá pọ̀ ju èmi lọ, ìwọ yóò sì wá ràn mí lọ́wọ́: ṣùgbọ́n bí ọwọ́ àwọn ọmọ Ámónì bá sì pọ̀ jù ọ́ lọ, èmi ó sì wá ràn ọ́ lọ́wọ́.

12. Mú ọkàn lè, jẹ́ kí a ṣe onígboyà nítorí àwọn ènìyàn wa, àti nítorí àwọn ìlú Ọlọ́run wa; Olúwa yóò sì ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ̀.”

13. Jóábù àti àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì bá àwọn ará Síríà pàdé ìjà: wọ́n sì sá níwájú rẹ̀.

14. Nígbà tí àwọn ọmọ Ámónì sì ríi pé àwọn ará Síríà sá, àwọn pẹ̀lú sì sá níwájú Ábíṣáì, wọ́n sì wọ inú ìlú lọ. Jóábù sì padà kúrò lẹ́yìn àwọn ọmọ Ámónì, ó sì wá sí Jérúsálẹ́mù.

Ìṣẹ́gun Lorí Ogun Ámónì àti Síríà Ní Hélámì.

15. Nígbà tí àwọn ará Síríà sì ríi pé Àwọn ṣubú níwájú Ísírẹ́lì: wọ́n sì kó ara wọn jọ

16. Hadadésérì sì ránṣẹ́, ó sì mú àwọn Síríà tí ó wà ní òkè odò jáde wá: wọ́n sì wá sí Hélámì; Sóbákì olórí ogun Hedareṣérì sì ṣe olórí wọn.

17. Nígbà tí a sọ fún Dáfídì, ó sì kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ, wọ́n sì kọjá Jọ́dánì, wọ́n sì wá sí Hélámì, Àwọn ará Síríà sì tẹ́ ogun kọjú sí Dáfídì, wọ́n sì bá a jà.

18. Àwọn ará Síríà sì sá níwájú Ísírẹ́lì, Dáfídì sì pa nínú àwọn ará Síríà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àwọn oníkẹ̀kẹ́, àti ọ̀kẹ́ méjì ẹlẹ́ṣin, wọ́n sì kọlu Sóbákì olórí ogun wọn, ó sì kú níbẹ́.

19. Nígbà tí gbogbo àwọn ọba tí ó wà lábẹ́ Hadadésérì sì ríi pé wọ́n di bíbì ṣubú níwájú Ísírẹ́lì, wọ́n sì bá Ísírẹ́lì làjà, wọ́n sì ń sìn wọ́n.Àwọn ará Síríà sì bẹ̀rù lati máa ran àwọn ọmọ Ámónì lọ́wọ́ mọ́.