Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 5:6-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ìwé tí ó mú lọ sọ́dọ̀ ọba Ísírẹ́lì kà pé: “Pẹ̀lú ìwé yìí èmi ń rán ìránṣẹ́ mi Námánì sí ọ pé o lè wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”

7. Bí ọba Ísírẹ́lì ti ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wí pé, “Èmi ha jẹ́ Ọlọ́run? Ǹjẹ́ èmi le pa kí n sì mú wá sí àyè padà? Kí ni ó dé tí eléyìí rán ènìyàn sí mi láti wo àrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ sàn, kí ẹ wo bí ó ti ń wá ọ̀nà láti wá ìjà pẹ̀lú mi!”

8. Nígbà tí Èlíṣà ènìyàn Ọlọ́run gbọ́ pé ọba Ísírẹ́lì ti ya aṣọ rẹ̀, ó sì rán iṣẹ́ yìí sí i pé: “Kí ni ó dé tí o fi fa aṣọ rẹ ya? Jẹ́ kí ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ mi. Òun yóò sì mọ̀ pé wòlíì wà ní Ísírẹ́lì.”

9. Bẹ́ẹ̀ ni Námánì sì lọ pẹ̀lú ẹṣin rẹ̀ àti kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà ilé Èlíṣà.

10. Èlíṣà rán ìránṣẹ́ láti lọ sọ fún un pé, “Lọ, wẹ̀ ara rẹ ní ìgbà méje ní odò Jọ́dánì, ẹran ara rẹ yóò sì tún padà bọ̀ sípò, ìwọ yóò sì mọ́.”

11. Ṣùgbọ́n Námánì lọ pẹ̀lú ìbúnú ó sì wí pé, “Mo lérò pé yóò sì dìde jáde wá nítòótọ́ sí mi, yóò sì pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run, fi ọwọ́ọ rẹ̀ lórí ibẹ̀ kí ó sì wo ẹ̀tẹ̀ mi sàn.

12. Ábánà àti Fápárì, odò Dámásíkù, dára ju gbogbo omi Ísírẹ́lì lọ? Ṣé èmi kò le wẹ̀ nínú wọn kí n sì mọ́?” Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà, ó sì lọ pẹ̀lú ìrunú.

13. Ìránṣẹ́ Námánì lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi, tí wòlíì bá ti sọ fún ọ láti ṣe ohun ńlá kan, ṣé ìwọ kì bá ti ṣe, mélòómélòó nígbà náà, nígbà tí ó sọ fún ọ pé, ‘Wẹ̀ kí o sì mọ́’!”

14. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ ó sì tẹ ara rẹ̀ bọ inú odò Jọ́dánì ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti sọ fún un, ẹran ara rẹ̀ sì tún padà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin kékeré.

15. Nígbà náà Námánì àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ padà lọ sí ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run. Ó sì dúró níwájú rẹ̀ ó sì wí pé, “Nísinsìnyí èmi mọ̀ pé kò sí Ọlọ́run ní gbogbo àgbáyé àyàfi ní Ísírẹ́lì nìkan. Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn láti ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ.”

16. Wòlíì náà dáhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láàyè, ẹni tí mo ń sìn, èmi kò ní gba ohun kan,” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Námánì rọ̀ ọ́ láti gbàá, ó kọ̀.

Ka pipe ipin 2 Ọba 5