Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 5:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Námánì jẹ́ olórí ogun ọba Árámù. Ó jẹ́ ènìyàn ńlá níwájú ọ̀gá rẹ̀, wọ́n sì bu ọlá fún un, nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ Olúwa fún wa ní ìṣẹ́gun fún Árámù. Ó jẹ́ alágbára, akọni ọkùnrin ṣùgbọ́n, ó dẹ́tẹ̀.

2. Nísinsìnyìí ẹgbẹgbẹ́ láti Árámù ti jáde lọ láti mú ọmọ obìnrin kékeré kan ní ìgbèkùn láti Ísírẹ́lì, ó sì sin ìyàwó Námánì.

3. Ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ obìnrin pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ọ̀gá mi lè rí wòlíì tí ó wà ní Samáríà! Yóò wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”

4. Námánì lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ ó sì wí fún un ohun tí ọmọbìnrin Ísírẹ́lì ti sọ.

5. “Ní gbogbo ọ̀nà, lọ,” ọba Árámù dá a lóhùn pé, “Èmi yóò fi ìwé ránṣẹ́ sí ọba Ísírẹ́lì.” Bẹ́ẹ̀ ni Námánì lọ, ó sì mú pẹ̀lú rẹ̀ talẹ́ńtì fàdákà mẹ́wàá, ẹgbẹ̀ta ìwọ̀n wúrà (6,000) àti ìpàrọ̀ aṣọ mẹ́wàá.

6. Ìwé tí ó mú lọ sọ́dọ̀ ọba Ísírẹ́lì kà pé: “Pẹ̀lú ìwé yìí èmi ń rán ìránṣẹ́ mi Námánì sí ọ pé o lè wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”

7. Bí ọba Ísírẹ́lì ti ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wí pé, “Èmi ha jẹ́ Ọlọ́run? Ǹjẹ́ èmi le pa kí n sì mú wá sí àyè padà? Kí ni ó dé tí eléyìí rán ènìyàn sí mi láti wo àrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ sàn, kí ẹ wo bí ó ti ń wá ọ̀nà láti wá ìjà pẹ̀lú mi!”

8. Nígbà tí Èlíṣà ènìyàn Ọlọ́run gbọ́ pé ọba Ísírẹ́lì ti ya aṣọ rẹ̀, ó sì rán iṣẹ́ yìí sí i pé: “Kí ni ó dé tí o fi fa aṣọ rẹ ya? Jẹ́ kí ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ mi. Òun yóò sì mọ̀ pé wòlíì wà ní Ísírẹ́lì.”

9. Bẹ́ẹ̀ ni Námánì sì lọ pẹ̀lú ẹṣin rẹ̀ àti kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà ilé Èlíṣà.

10. Èlíṣà rán ìránṣẹ́ láti lọ sọ fún un pé, “Lọ, wẹ̀ ara rẹ ní ìgbà méje ní odò Jọ́dánì, ẹran ara rẹ yóò sì tún padà bọ̀ sípò, ìwọ yóò sì mọ́.”

11. Ṣùgbọ́n Námánì lọ pẹ̀lú ìbúnú ó sì wí pé, “Mo lérò pé yóò sì dìde jáde wá nítòótọ́ sí mi, yóò sì pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run, fi ọwọ́ọ rẹ̀ lórí ibẹ̀ kí ó sì wo ẹ̀tẹ̀ mi sàn.

Ka pipe ipin 2 Ọba 5