Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 4:22-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ó pe ọkọ rẹ̀ ó sì wí pé, “Jọ̀wọ́ rán ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan kí èmi kí ó lè lọ sí ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run kíákíá kí n sì padà.”

23. “Kí ni ó dé tí o fi fẹ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ lónìí?” Ó béèrè. “Kì í ṣe oṣù túntún tàbí ọjọ́ ìsinmi.” ó wí pé“Gbogbo rẹ̀ ti dára”

24. Ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Má a nìṣó; má ṣe dẹsẹ̀ dúró dè mí àyàfi tí mo bá sọ fún ọ.”

25. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì jáde wá, ó sì wá sọ́dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ní orí òkè Kámẹ́lì.Nígbà tí ó sì rí i láti òkèrè, ènìyàn Ọlọ́run sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Géhásì, “Wò ó! Ará Ṣúnémù nì!

26. Sáré lọ pàdé rẹ̀ kí o sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ‘Ṣé o wà dáadáa? Ṣé ọkọ rẹ wà dáadáa? Ṣé ọmọ rẹ wà dáadáa?’ ”Ó wí pé, “Gbogbo nǹkan wà dáadáa.”

27. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ní orí òkè, ó gbá a ní ẹṣẹ̀ mú. Géhásì wá láti wá lé e dànù, ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run wí pé, “Fi í sílẹ̀! Ó wà nínú ìpọ́njú, Kíkorò, ṣùgbọ́n Olúwa fi pamọ́ fún mi kò sì sọ ìdí rẹ̀ fún mi.”

28. “Ṣé mo béèrè ọmọ lọ́wọ́ rẹ, Olúwa mi?” Obìnrin náà wí pé, “Ṣé mi ò sọ fún ọ pe kí o, ‘Má ṣe fa ìrètí mi sókè’?”

29. Èlíṣà wí fún Géhásì pé, “Ká agbádá rẹ sínú ọ̀já àmùrè, mú ọ̀pá mi sí ọwọ́ rẹ kí o sì sáré. Tí o bá pàdé ẹnikẹ́ni má ṣe kí i, tí ẹnikẹ́ni bá kí ọ, má ṣe dá a lóhùn, fi ọ̀pá náà lé ojú ọmọ ọkùnrin náà.”

30. Ṣùgbọ́n ìyá ọmọ náà wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láàyè àti gẹ́gẹ́ bí ó ti wà láàyè, èmi kò níí fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì dìde ó sì tẹ̀lé e.

31. Géhásì sì ń lọ síbẹ̀ ó sì fi ọ̀pá náà lé ojú ọmọ náà, ṣùgbọ́n kò sí ohùn dídún. Bẹ́ẹ̀ ni Géhásì padà lọ láti lọ bá Èlíṣà láti sọ fún un pé, “Ọmọ ọkùnrin náà kò tí ì dìde.”

32. Nígbà tí Èlíṣà dé inú ilé, níbẹ̀ ni òkú ọmọ ọkùnrin náà dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn.

33. Ó sì wọ ilé, ó sì ti ilẹ̀kùn mọ́ àwọn méjèèjì ó sì gbàdúrà sí Olúwa.

34. Nígbà náà ó dé orí ibùsùn, ó sùn sórí ọmọ ọkùnrin náà, ẹnu sí ẹnu, ojú sí ojú, ọwọ́ sí ọwọ́. Gẹ́gẹ́ bí ó ti nà ara rẹ̀ lórí rẹ̀, ara ọmọ náà sì gbóná.

35. Èlíṣà yípadà lọ, ó sì rìn padà ó sì jáde wá sínú ilé nígbà náà ó sì padà sí orí ibùsùn ó sì tún nà lé e ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Ọmọ ọkùnrin náà sì sín ní ìgbà méje ó sì sí ojú rẹ̀.

36. Èlíṣà sì pe Géhásì ó sì wí pé, “Pe ará Súnémù.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó dé, ó wí pé, “Gba ọmọ rẹ.”

Ka pipe ipin 2 Ọba 4