Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 20:2-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Heṣekáyà yí ojú rẹ̀ padà sí ògiri ó sì gbàdúrà sí Olúwa pé,

3. “Rántí, Olúwa mi, bí èmi ṣe rìn níwájú rẹ àti pẹ̀lú bí èmi ṣe jẹ́ olóòtọ́ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn ìfọkànsìn mi tí èmi sì ti ṣe ohun tí ó dára níwájú rẹ.” Heṣekáyà sunkún kíkorò.

4. Kí ó tó di wí pé Àìṣáyà jáde kúrò ní àárin àgbàlá ààfin, ọ̀rọ̀ Olúwa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé.

5. “Lọ padà kí o sì sọ fún Heṣekáyà, olórí àwọn ènìyàn mi pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run baba rẹ Dáfídì sọ: Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ: Èmi yóò wò ó sàn. Ní ọjọ́ kẹta láti ìsinsìnyìí, ìwọ yóò lọ sókè ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

6. Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀dógún kún ọjọ́ ayé rẹ. Èmi yóò sì gbà ọ́ àti ìlú ńlá yìí láti ọwọ́ ọba Ásíríà. Èmi yóò sì dábòbò ìlú yìí nítorí ti èmi tìkára mi àti nítorí ti Dáfídì ìránṣẹ́ mi.’ ”

7. Nígbà náà ni Àìṣáyà wí pé, “Mú ọ̀pọ̀tọ́ tí a sù bí i gàrí.” Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì fi sí owo náà, ara rẹ̀ sì yá.

8. Heṣekáyà sì béèrè lọ́wọ́ Àìṣáyà pé, “Kí ni yóò jẹ́ àmìn pé Olúwa yóò wò mí sàn àti wí pé èmi yóò lọ sókè sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa láti ọjọ́ kẹta títí di òní?”

9. Àìṣáyà dáhùn pé, “Èyí ni àmìn tí Olúwa fún ọ wí pé Olúwa yóò ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí: kí òjìji lọ ṣíwájú ìgbésẹ̀ mẹ́wàá, tàbí kí ó padà lọ ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá?”

Ka pipe ipin 2 Ọba 20