Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 6:6-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ṣùgbọ́n nísinyìí èmi ti yan Jérúsálẹ́mù, kí orukọ mi leè wà níbẹ̀, èmi sì ti yan Dáfídì láti jọba lórí Ísírẹ́lì ènìyàn mi.’

7. “Baba mi Dáfídì ti ní-in lọ́kàn láti kọ́ tẹ́ḿpìlì fún orúkọ Olúwa, àní Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

8. Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Dáfídì baba mi pé, ‘Nítorí tí ó wà ní ọkàn rẹ láti kọ́ tẹ́ḿpìlì yìí fún orúkọ mi, ìwọ ṣe ohun dáradára láti ní èyí ní ọkàn rẹ̀.

9. Ṣùgbọ́n síbẹ̀, ìwọ kọ́ ni yóò kọ́ tẹ́ḿpìlì náà, bí kò ṣe ọmọ rẹ, ẹni tí o jẹ́ ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ rẹ: òun ni yóò kọ́ tẹ́ḿpìlì fún orúkọ mi.’

10. “Olúwa sì ti mú ìléri rẹ̀ ṣẹ. Èmi ti dìde ní ipò Dáfídì baba mi, a sì gbé mi ka ìtẹ́ Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣe ìlérí, èmi sì ti kọ́ tẹ́ḿpìlì fún orúkọ Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

11. Níbẹ̀ ni èmi sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa sí, nínú èyí ti májẹ̀mú ti Olúwa bá àwọn Ísirẹ́lì ènìyàn mi dá wà.”

12. Nígbà naà ni Sólómónì dúró níwájú pẹpẹ Olúwa, ní iwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Isírẹ́lì, ó sì tẹ́ ọwọ́ọ rẹ̀ méjèèjì.

13. Sólómónì ṣe àga idẹ kan tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ márùn ún fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gíga, a gbé e sí àárin àgbàlá ti òde. Ó sì dúró ní orí rẹ̀, àti pé ó kúnlẹ̀ lórí eékún rẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Isírẹ́lì, ó sì tẹ́ ọwọ́ọ rẹ̀ méjèèjì sí òkè ọ̀run.

14. Ó wí pé:“Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kò sí Ọlọ́run tí ó dà bí rẹ ní ọ̀run àti ní ayé: ìwọ tí o pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ń fi tọkàntọkàn wọn rìn ní ọ̀nà rẹ.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 6