Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 5:5-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí náà gòkè àti àgọ́ ìpàdé àti gbogbo ohun èlò mímọ́ tí ó wà nínú àgọ́. Àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì ni ó mú wọn gòkè wá;

6. Nígbà náà ni ọba Sólómónì àti gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì tí ó pé jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wà níwájú àpótí ẹ̀rí náà wọ́n sì fi àgùntàn àti màlúù tí a kò leè kà tán rúbọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò leè mọ iye wọn tán nítorí bí wọ́n ti pọ̀ tó.

7. Nígbà náà ni àwọn àlùfáà gbé àpótí ẹ̀ri ti májẹ̀mú Olúwa wá sí ipò rẹ̀, sí ibi inú lọ́hùn ún ilé Olúwa, ibi mímọ́ jùlọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù.

8. Àwọn Kérúbù na ìyẹ́ wọn bo ibi àpótí ẹ̀rí náà àti àwọn ọ̀pá tí ó gbé e ró.

9. Àwọn ọ̀pá rẹ̀ náà gùn tó bẹ́ẹ̀ tí a fi rí ori àwọn ọ̀pá náà láti ibi àpótí ẹ̀rí náà níwájú ibi mímọ́ náà, ṣùgbọ́n a kò rí wọn lóde. Níbẹ̀ ni ó sì wà títí di òní yìí.

10. Kò sí ohun kan nínú àpótí ẹ̀rí náà bí kò ṣe síléètì méjì tí Mósè fi sínú rẹ̀ ní Hórébù, ní ìgbà tí Olúwa fi bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde wá láti ilẹ̀ Éjíbítì.

11. Lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà jáde wá láti ibi mímọ́. Gbogbo àwọn àlùfáà tí ó wà níbẹ̀ ni ó ya ara wọn sí mímọ́ láìbìkítà fún ìpín wọn.

12. Gbogbo àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ ọ̀kọrin: Ásáfù, Hémánì, Jédútúnì àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ẹbí wọn, wọ́n dúró ní igun ìlà oòrùn pẹpẹ náà wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ túntún wọ́n ń lo ohun èlò orin kínnbálì, hápù àti líà. Ìwọ̀n ọgọ́fà àwọn àlùfaà tí wọ́n ń fun ìpè ni wọ́n tẹ̀lé wọn.

13. Àwọn afọ̀npè àti àwọn ọ̀kọrin pa ohùn wọn pọ̀ sí ọ̀kan soso, láti fi ìyìn àti ọpẹ́ fun Olúwa. Wọ́n fi ìpè, kíḿbálì àti àwọn ohun èlò orin mìíràn mọ́ ọn, wọ́n gbé ohùn wọn sokè láti fi yin Olúwa, wọ́n ń kọrin pé:“Ó dára;ìfẹ́ rẹ̀ wà títí láéláé.”Nígbà náà ni ìkùku ojú ọ̀run kún inú tẹ́ḿpìlì Olúwa,

14. Tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn àlùfáà kò leè ṣiṣẹ́ ìsìn wọn nítorí ìkùku náà, nítorí ògo Olúwa kún inú tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 5