Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 7:21-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Ó sì gbé àwọn ọ̀wọn náà ró ní ìloro tẹ́ḿpìlì, ó sì pe orúkọ ọ̀wọ̀n tí ó wà ní gúṣù ní Járánì àti èyí tí ó wà ní àríwá ní Bóásì.

22. Àwọn ìparí lókè sì jẹ́ àwòrán lílì. Bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ ti àwọn ọ̀wọ̀n sì parí.

23. Ó sì ṣe agbádá dídá, ó ṣe bíríkítí, ó wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti etí kan dé èkejì àti ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní gíga rẹ̀. Ó sì gba okùn ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ láti wọ̀n yíí ká.

24. Ní ìṣàlẹ̀ etí rẹ̀, kókó wà yíi ká, mẹ́wàá nínú ìgbọ̀nwọ́ kan. Ó yí agbádá náà káàkiri, a dá kókó náà ní ọ̀wọ́ méjì, nígbà tí a dá a.

25. Ó sì dúró lórí màlúù méjìlá, mẹ́ta kọjú sí àríwá, mẹ́ta sì kọjú sí ìwọ̀ oòrùn, mẹ́ta kọjú sí gúṣù, mẹ́ta sì kọjú sí ìlà oòrùn. Agbada náà sì jókòó lórí wọn, gbogbo apá ẹ̀yìn wọn sì ń bẹ nínú.

26. Ó sì nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ sì dàbí etí ago, bí ìtànná lílì. Ó sì gba ẹgbàá (2,000) ìwọ̀n Bátì.

27. Ó sì tún ṣe ẹṣẹ̀ idẹ tí a lè gbé mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gígùn, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní ìbú àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gíga.

28. Báyìí ni a sì ṣe ẹsẹ̀ náà: Wọ́n ní àlàfo ọnà àárin tí a so mọ́ agbede-méjì ìpàdé etí.

29. Lórí àlàfo ọnà àárin tí ó wà lágbedeméjì ni àwòrán kìnnìún, màlúù, àti àwọn kérúbù wà, àti lórí ìpàdé etí bákan náà. Lókè àti nísàlẹ̀ àwọn kìnnìún, màlúù sì ni iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ wà.

30. Ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan sì ni kẹ̀kẹ́ idẹ mẹ́rin pẹ̀lú ọ̀pá kẹ̀kẹ́ idẹ, ọ̀kọ̀ọ̀kan ni ó ní ìfẹsẹ̀tẹ̀ lábẹ́, tí a gbẹ́, iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ wà ní ìhà gbogbo rẹ̀.

31. Nínú ẹsẹ̀ náà ẹnu kan wà tí ó kọ bíríkítí tí ó jìn ní ìgbọ̀nwọ́ kan. Ẹnu yìí ṣe róbótó àti pẹ̀lú iṣẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀. Ní àyíká ẹnu rẹ̀ ni ohun ọnà gbígbẹ́ wà. Àlàfo ọ̀nà àárin ẹsẹ̀ náà sì ní igun mẹ́rin, wọn kò yíká.

32. Kẹ̀kẹ́ mẹ́rin sì wà nísàlẹ̀ àlàfo ọ̀nà àárin a sì so ọ̀pá àyíká kẹ̀kẹ́ náà mọ́ ẹsẹ̀ náà. Gíga àyíká kẹ̀kẹ́ kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀.

33. A sì ṣe àyíká kẹ̀kẹ́ náà bí i iṣẹ́ kẹ̀kẹ́; igi ìdalu, ibi ihò, ibi ìpàdé, àti ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn, gbogbo wọn sì jẹ́ irin dídà.

34. Ẹṣẹ̀ kọ̀ọ̀kan sì ní ìfẹsẹ̀tẹ̀ mẹ́rin, ọ̀kan ní igun kọ̀ọ̀kan, tí ó yọrí jáde láti ẹṣẹ̀.

35. Lókè ẹṣẹ̀ náà ni àyíká kan wà tí ó jẹ́ ààbọ̀ ìgbọ̀nwọ́ ní jíjìn. Ẹ̀gbẹ́ etí rẹ̀ àti àlàfo ọ̀nà àárin rẹ̀ ni a ṣo mọ́ òkè ẹsẹ̀ náà.

Ka pipe ipin 1 Ọba 7