Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 21:21-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. ‘Èmi yóò mú ibi wá sórí rẹ. Èmi yóò sì mú ìran rẹ kúrò, èmi yóò sì ké kúrò lọ́dọ̀ Áhábù gbogbo ọmọdé ọkùnrin, àti ọmọ ọ̀dọ̀, àti òmìnira ní Ísírẹ́lì.

22. Èmi yóò ṣe ilé rẹ bí ilé Jéróbóámù, ọmọ Nébátì, àti bí ilé Bááṣà, ọmọ Áhíjà, nítorí ìwọ ti mú mi bínú, ìwọ sì ti mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀.’

23. “Àti níti Jésébélì pẹ̀lú Olúwa wí pé: ‘Àwọn ajá yóò jẹ Jésébélì nínú yàrá Jésírẹ́lì.’

24. “Àwọn ajá yóò jẹ ẹni Áhábù tí ó kú ní ìlú, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ àwọn ẹni tí ó kú ní ìgbẹ́.”

25. (Kò sí ẹnìkan bí Áhábù tí ó ta ara rẹ̀ láti ṣe búburú níwájú Olúwa, ẹni tí Jésébélì aya rẹ̀ ń tì.

26. Ó sì ṣe ohun ìríra gidigidi ní títọ òrìṣà lẹ́yìn, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí àwọn ará Ámórì ti ṣe, tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.)

27. Nígbà tí Áhábù sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ sí ara rẹ̀, ó sì gba ààwẹ̀. Ó sì dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì ń lọ jẹ́ ẹ́.

28. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Èlíjà ará Tíṣíbì wá wí pé:

29. “Ǹjẹ́ ìwọ ti rí bí Áhábù ti rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi? Nítorí tí ó ti rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀, èmi kì yóò mú ibi náà wá ní ọjọ́ rẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò mú u wá sí ilé rẹ̀ ní ọjọ́ ọmọ rẹ̀.”

Ka pipe ipin 1 Ọba 21