Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 18:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ní ọdún kẹta, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Èlíjà wá pé: “Lọ, kí o sì fi ara rẹ̀ hàn fún Áhábù, èmi yóò sì rọ òjò sórí ilẹ̀.”

2. Bẹ́ẹ̀ ni Èlíjà lọ fi ara rẹ̀ han Áhábù.Ìyàn ńlá sì mú ní Samáríà,

3. Áhábù sì ti pe Ọbadíàh, ẹni tí ń ṣe olórí ilé rẹ̀. Ọbadíà sì bẹ̀rù Olúwa gidigidi.

4. Nígbà tí Jésébélì sì ń pa àwọn wòlíì Olúwa kúrò, Ọbadíà sì mú ọgọ́rùn ún wòlíì, ó sì fi wọ́n pamọ́ sínú ihò òkúta, àádọ́ta ní ihò kọ̀ọ̀kan, ó sì fi àkàrà pẹ̀lú omi bọ́ wọn.

5. Áhábù sì ti wí fún Ọbadíà pé, “Lọ sí gbogbo ilẹ̀ sí orísun omi gbogbo àti sí ilẹ̀ gbogbo. Bóyá àwa lè rí koríko láti gba àwọn ẹsin àti àwọn ìbááka là, kí a má báà ṣòfò àwọn ẹranko pátapáta.”

6. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì pín ilẹ̀ tí wọ́n fẹ́ dé láàrin ara wọn, Áhábù gba ọ̀nà kan lọ, Ọbadíà sì gba ọ̀nà mìíràn lọ.

7. Bí Ọbadíà sì ti ń rìn lọ, Èlíjà sì pàdé rẹ̀. Ọbadíà sì mọ̀ ọ́, ó dojú bolẹ̀, ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ni ní tòótọ́, Èlíjà, Olúwa mi?”

8. Èlíjà sì dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, lọ kí o sọ fún olúwa rẹ pé, ‘Èlíjà ń bẹ níhìn ín.’ ”

9. Ọbadíà sì béèrè pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ kí ni mo ha dá tí ìwọ fi ń fi ìránṣẹ́ rẹ lé Áhábù lọ́wọ́ láti pa?

10. Mo mọ̀ dájú pé bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti ń bẹ, kò sí orílẹ̀ èdè tàbí ìjọba kan tí olúwa mi kò ti rán ènìyàn lọ láti wò ọ́. Àti nígbà tí orílẹ̀ èdè tàbí ìjọba kan bá wí pé o kò sí, òun a sì mú kí wọ́n búra wí pé wọn kò rí ọ.

Ka pipe ipin 1 Ọba 18