Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 1:30-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. Lónìí dandan ni èmi yóò gbé ohun tí mo ti fi Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì búra fún yọ pé: Sólómónì ọmọ rẹ ni yóò jẹ ọba lẹ́yìn mi, àti pé yóò jókòó lórí ìtẹ́ mi ní ipò mi.”

31. Nígbà náà ni Bátíṣébà tẹriba, ó sì kúnlẹ̀ níwájú ọba pé, “Kí Olúwa mi Dáfídì ọba kí ó pẹ́!”

32. Dáfídì ọba sì wí pé, “Ẹ pe Sadókù àlùfáà wọlé fún mi àti Nátanì wòlíì àti Bẹ́náyà ọmọ Jéhóíádà.” Nígbà tí wọ́n wá ṣíwájú ọba,

33. Ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ mú àwọn ìránṣẹ́ Olúwa yín pẹ̀lú yín kí ẹ sì mú kí Sólómónì ọmọ mi kí ó gun ìbaka mi, kí ẹ sì mú-un sọ̀kalẹ̀ wá sí Gíhónì.

34. Níbẹ̀ ni Sádókù àlùfáà àti Nátanì wòlíì fi òróró yàn án ní ọba lórí Ísírẹ́lì. Ẹ fọn fèrè, kí ẹ sì ké pé, ‘Kí Sólómónì ọba kí ó pẹ́!’

35. Nígbà náà ni kí ẹ sì gòkè pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì wá, kí ó sì jókòó sórí ìtẹ́ mi, kí ó sì jọba ní ipò mi. Èmi ti yàn án ní ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà.”

36. Bénáyà ọmọ Jéhóíádà sì dá ọba lóhùn pé, “Àmín! Kí Olúwa Ọlọ́run Olúwa mi ọba, kéde rẹ̀ bẹ́ẹ̀

37. Bí Olúwa ti wà pẹ̀lú Olúwa mi ọba, bẹ́ẹ̀ ni kí ó wà pẹ̀lú Sólómónì kí ó lè mú kí ìjọba rẹ̀ pẹ́ ju ìtẹ́ Olúwa mi Dáfídì Ọba lọ!”

38. Nígbà náà ni Sadókù àlùfáà, Nátanì wòlíì, Bénáyà ọmọ Jéhóiádà, àwọn ará Kérétì àti Pélétì sì sọ̀kalẹ̀ wá wọ́n sì gbé Sólómónì gun ìbaka Dáfídì ọba wá sí Gíhónì.

39. Sádókù àlùfáà sì mú ìwo òróró láti inú àgọ́, ó sì dà á sí Sólómónì lórí. Nígbà náà ni wọ́n sì fọn fèrè, gbogbo àwọn ènìyàn sì ké pé, “Kí Sólómónì ọba kí ó pẹ́!”

40. Gbogbo ènìyàn sì gòkè tọ̀ ọ́ lẹ́yìn wọ́n ń fọn ìpè, wọ́n sì ń yọ ayọ̀ ńlá, tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ mì fún ìró wọn.

Ka pipe ipin 1 Ọba 1