Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 1:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Dáfídì ọba di arúgbó, ọjọ́ rẹ̀ sì pọ̀, ara rẹ̀ kò le è móoru bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n da ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣọ bò ó.

2. Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wí fún un pé, “Ẹ jẹ́ kí a wá ọ̀dọ́mọbìnrin wúndíá kan kí ó dúró ti ọba, kì ó sì máa tọ́jú rẹ̀. Kí ó dùbúlẹ̀ ní àyà rẹ̀ kí ara ọba Olúwa wa lè móoru.”

3. Nígbà náà ni wọ́n lọ jákèjádo ilẹ̀ Ísírẹ́lì láti wá ọ̀dọ́mọbìnrin arẹwà, wọ́n sì rí Ábíságì, ará Ṣúnémù, wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ ọba.

4. Ọmọbìnrin náà rẹwà gidigidi; ó sì ń ṣe ìtọ́jú ọba, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, ṣùgbọ́n ọba kò sì bá a lò pọ̀.

5. Àdóníjà ẹni tí ìyá rẹ̀ ń ṣe Hágátì sì gbé ara rẹ̀ ga, ó sì wí pé, “Èmi yóò jẹ ọba.” Ó sì sètò kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́sin, pẹ̀lú àádọ́ta ọkùnrin láti máa sáré níwájú rẹ̀.

6. (Baba rẹ̀ kò bà á nínú jẹ́ rí nípa bíbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí ìwọ fi hùwà báyìí?” Ó sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin, òun ni a bí lé Ábúsálómù.)

7. Àdóníjà sì gbérò pẹ̀lú Jóábù, ọmọ Ṣérúyà àti Ábíátarì àlùfáà, wọ́n sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un.

8. Ṣùgbọ́n Ṣádókù àlùfáà, Bẹ́náyà ọmọ Jóhóíádà, Nátanì wòlíì, Ṣímè àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Rélì àti olórí ogun Dáfídì ni kò darapọ̀ mọ́ Àdóníjà

9. Nígbà náà ni Àdóníjà fi àgùntàn àti màlúù àti ẹran ọ̀sìn tí ó sanra rúbọ níbi òkúta Sóhélétì tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Énrógélì. Ó sì pe gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ ọba, àti gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ ọba.

10. Ṣùgbọ́n kò pe Nátanì Wòlíì tàbí Bénáyà tàbí àwọn olórí tàbí Sólómónì arákùnrin rẹ̀.

11. Nígbà náà ni Nátanì bèrè lọ́wọ́ Bátíṣébà, ìyá Sólómọ́nì pé, “Ǹjẹ́ ìwọ kò gbọ́ pé Àdóníjà, ọmọ Hágítì ti jọba láìjẹ́ pé Dáfídì Olúwa wa mọ̀ síi?

12. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, jẹ́ kí èmi gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn bí ìwọ ṣe lè gba ẹ̀mí rẹ là àti ẹ̀mí ọmọ rẹ Sólómónì.

Ka pipe ipin 1 Ọba 1