Nígbà náà ni wọ́n lọ jákèjádo ilẹ̀ Ísírẹ́lì láti wá ọ̀dọ́mọbìnrin arẹwà, wọ́n sì rí Ábíságì, ará Ṣúnémù, wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ ọba.