Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 22:17-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Nitoripe, emi o sọ ọ di ẹni nla gidigidi, emi o si ṣe ohunkohun ti iwọ wi fun mi: nitorina wá, emi bẹ̀ ọ, fi awọn enia yi bú fun mi.

18. Balaamu si dahùn o si wi fun awọn iranṣẹ Balaki pe, Balaki iba fẹ́ fun mi ni ile rẹ̀ ti o kún fun fadaká ati wurà, emi kò le rekọja ọ̀rọ OLUWA Ọlọrun mi, lati ṣe ohun kekere tabi nla.

19. Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ nyin, ẹ wọ̀ nihin pẹlu li oru yi, ki emi ki o le mọ̀ eyiti OLUWA yio wi fun mi si i.

20. Ọlọrun si tọ̀ Balaamu wá li oru, o si wi fun u pe, Bi awọn ọkunrin na ba wá pè ọ, dide, bá wọn lọ; ṣugbọn kìki ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ, eyinì ni ki iwọ ki o ṣe.

21. Balaamu si dide li owurọ̀, o si dì kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ ni gãri, o si bá awọn ijoye Moabu lọ.

22. Ibinu Ọlọrun si rú nitoriti o lọ: angeli OLUWA si duro loju ọ̀na lati di i lọ̀na. Njẹ on gùn kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, awọn iranṣẹ rẹ̀ mejeji si wà pẹlu rẹ̀.

23. Kẹtẹkẹtẹ na si ri angeli OLUWA duro loju ọ̀na, idà rẹ̀ fifàyọ si wà li ọwọ́ rẹ̀: kẹtẹkẹtẹ na si yà kuro loju ọ̀na, o si wọ̀ inu igbẹ́: Balaamu si lù kẹtẹkẹtẹ na, lati darí rẹ̀ soju ọ̀na.

24. Nigbana ni angeli OLUWA duro li ọna toro ọgbà-àjara meji, ogiri mbẹ ni ìha ihin, ati ogiri ni ìha ọhún.

25. Kẹtẹkẹtẹ na si ri angeli OLUWA, o fún ara rẹ̀ mọ́ ogiri, o si fún ẹsẹ̀ Balaamu mọ́ ogiri: on si tun lù u.

26. Angeli OLUWA si tun sun siwaju, o si tun duro ni ibi tõro kan, nibiti àye kò sí lati yà si ọwọ́ ọtún tabi si òsi.

27. Nigbati kẹtẹkẹtẹ na si ri angeli OLUWA, o wólẹ̀ labẹ Balaamu: ibinu Balaamu si rú pupọ̀, o si fi ọpá lu kẹtẹkẹtẹ na.

28. OLUWA si là kẹtẹkẹtẹ na li ohùn, o si wi fun Balaamu pe, Kini mo fi ṣe ọ, ti iwọ fi lù mi ni ìgba mẹta yi?

29. Balaamu si wi fun kẹtẹkẹtẹ na pe, Nitoriti iwọ fi mi ṣẹsin: idà iba wà li ọwọ́ mi, nisisiyi li emi iba pa ọ.

30. Kẹtẹkẹtẹ na si wi fun Balaamu pe, Kẹtẹkẹtẹ rẹ ki emi ṣe, ti iwọ ti ngùn lati ìgba ti emi ti ṣe tirẹ titi di oni? emi a ha ma ṣe si ọ bẹ̃ rí? On si dahùn wipe, Ndao.

Ka pipe ipin Num 22