Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Neh 9:14-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Iwọ si mu ọjọ isimi mimọ rẹ di mimọ̀ fun wọn, o si paṣẹ ẹkọ́, ilana, ati ofin fun wọn, nipa ọwọ Mose iranṣẹ rẹ.

15. O si fun wọn li onjẹ lati ọrun wá fun ebi wọn, o si mu omi lati inu apata wá fun orungbẹ wọn, o si ṣe ileri fun wọn pe, ki nwọn lọ ijogun ilẹ na ti iwọ ti bura lati fi fun wọn.

16. Ṣugbọn awọn ati awọn baba wa hu ìwa igberaga, nwọn si mu ọrùn wọn le, nwọn kò si gba ofin rẹ gbọ́.

17. Nwọn si kọ̀ lati gbọràn, bẹ̃ni nwọn kò ranti iṣẹ iyanu ti iwọ ṣe li ãrin wọn; ṣugbọn nwọn mu ọrùn wọn le, ninu ìṣọtẹ wọn, nwọn yan olori lati pada si oko-ẹrú wọn: ṣugbọn iwọ li Ọlọrun ti o mura lati dariji, olore ọfẹ, ati alãnu, o lọra lati binu, o si ṣeun pipọ̀, o kò si kọ̀ wọn silẹ.

18. Nitõtọ nigbati nwọn ṣe ẹgbọrọ-malu didà, ti nwọn si wipe, Eyi li Ọlọrun rẹ ti o mu ọ gòke ti Egipti jade wá, nwọn si ṣe imunibinu nla.

19. Ṣugbọn iwọ, ninu ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ, kò kọ̀ wọn silẹ li aginju, ọwọ̀n kũkũ kò kuro lọdọ wọn lojojumọ lati ṣe amọna wọn, bẹ̃ si li ọwọ̀n iná lati fun wọn ni imọlẹ li oru li ọ̀na ti nwọn iba rìn.

20. Iwọ fun wọn li ẹmi rere rẹ pẹlu lati kọ́ wọn, iwọ kò si gba manna rẹ kuro li ẹnu wọn, iwọ si fun wọn li omi fun orungbẹ wọn.

21. Nitotọ, ogoji ọdun ni iwọ fi bọ́ wọn li aginju, nwọn kò si ṣe alaini; aṣọ wọn kò gbó, ẹsẹ wọn kò si wú.

22. Pẹlupẹlu iwọ fi ijọba ati orilẹ-ède fun wọn, o si pin wọn si ìha gbogbo, bẹ̃ni nwọn jogun ilẹ Sihoni, ati ilẹ ọba Heṣboni, ati ilẹ Ogu, ọba Baṣani.

23. Awọn ọmọ wọn pẹlu ni iwọ sọ di pipọ bi irawọ ọrun, o si mu wọn wá ilẹ na sipa eyiti o ti leri fun awọn baba wọn pe: ki nwọn lọ sinu rẹ̀ lati gbà a.

24. Bẹ̃li awọn ọmọ na wọ inu rẹ̀ lọ, nwọn si gbà ilẹ na, iwọ si tẹ ori awọn ara ilẹ na ba niwaju wọn, awọn ara Kenaani, o si fi wọn le ọwọ wọn, pẹlu ọba wọn, ati awọn enia ilẹ na, ki nwọn ki o le fi wọn ṣe bi o ti wù wọn.

25. Nwọn si gbà ilu alagbara, ati ilẹ ọlọra, nwọn si gbà ilẹ ti o kún fun ohun rere, kanga, ọgba-ajara, ọgba-olifi, ati igi eleso, li ọ̀pọlọpọ: bẹ̃ni nwọ́n jẹ, nwọn si yo, nwọ́n sanra, nwọn si ni inu-didùn ninu ore rẹ nla.

26. Ṣugbọn nwọn ṣe alaigbọràn, nwọn si ṣọ̀tẹ si ọ, nwọn si gbe ofin rẹ sọ si ẹ̀hin wọn, nwọn si pa awọn woli rẹ ti nsọ fun wọn lati yipada si ọ, nwọn si ṣe imunibinu nla.

27. Nitorina ni iwọ fi wọn le ọwọ awọn ọta wọn, ti o pọn wọn loju, ati li akoko ipọnju wọn, nigbati nwọn kigbe pè ọ, iwọ gbọ́ lati ọrun wá; ati gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ, iwọ fun wọn li olugbala, ti nwọn gbà wọn kuro lọwọ awọn ọta wọn.

28. Ṣugbọn li ẹhin ti nwọn ni isimi, nwọn si tun ṣe buburu niwaju rẹ: nitorina ni iwọ fi wọn le ọwọ awọn ọta wọn, tobẹ̃ ti nwọn jọba li ori wọn: ṣugbọn nigbati nwọn pada, ti nwọn si kigbe pè ọ, iwọ gbọ́ lati ọrun wá, ọ̀pọlọpọ ìgba ni iwọ si gbà wọn gẹgẹ bi ãnu rẹ.

29. Iwọ si jẹri gbè wọn ki iwọ ki o le tun mu wọn wá sinu ofin rẹ, ṣugbọn nwọn hu ìwa igberaga, nwọn kò si fi eti si ofin rẹ, nwọn si ṣẹ̀ si idajọ rẹ (eyiti bi enia ba ṣe on o yè ninu wọn), nwọn si gún èjika, nwọn mu ọrùn wọn le, nwọn kò si fẹ igbọ́.

30. Sibẹ ọ̀pọlọpọ ọdun ni iwọ fi mu suru fun wọn ti o si fi ẹmi rẹ jẹri gbè wọn ninu awọn woli rẹ: sibẹ̀ nwọn kò fi eti silẹ: nitorina ni iwọ ṣe fi wọn le ọwọ awọn enia ilẹ wọnni.

Ka pipe ipin Neh 9