Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 4:8-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi Joṣua ti paṣẹ, nwọn si gbé okuta mejila lati inu ãrin Jordani lọ, bi OLUWA ti wi fun Joṣua, gẹgẹ bi iye ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli; nwọn si rù wọn kọja pẹlu wọn lọ si ibùsun, nwọn si gbé wọn kalẹ nibẹ̀.

9. Joṣua si tò okuta mejila jọ lãrin Jordani, ni ibi ti ẹsẹ̀ awọn alufa ti o rù apoti majẹmu na gbé duro: nwọn si mbẹ nibẹ̀ titi di oni-oloni.

10. Nitoriti awọn alufa ti o rù apoti na duro lãrin Jordani, titi ohun gbogbo fi pari ti OLUWA palaṣẹ fun Joṣua lati sọ fun awọn enia, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Mose palaṣẹ fun Joṣua: awọn enia na si yára nwọn si rekọja.

11. O si ṣe, nigbati gbogbo awọn enia na rekọja tán, ni apoti OLUWA rekọja, ati awọn alufa, li oju awọn enia.

12. Awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, si rekọja ni ihamọra niwaju awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi Mose ti sọ fun wọn:

13. Ìwọn ọkẹ meji enia ti o mura ogun, rekọja niwaju OLUWA fun ogun, si pẹtẹlẹ̀ Jeriko.

14. Li ọjọ́ na OLUWA gbé Joṣua ga li oju gbogbo Israeli: nwọn si bẹ̀ru rẹ̀, gẹgẹ bi nwọn ti bẹ̀ru Mose li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo.

15. OLUWA si wi fun Joṣua pe,

16. Paṣẹ fun awọn alufa ti o rù apoti ẹri nì pe, ki nwọn ki o ti inu Jordani jade.

17. Nitorina Joṣua paṣẹ fun awọn alufa wipe, Ẹ ti inu Jordani jade.

18. O si ṣe, nigbati awọn alufa ti o rù apoti majẹmu OLUWA ti ãrin Jordani jade, ti awọn alufa si gbé atẹlẹsẹ̀ wọn soke si ilẹ gbigbẹ, ni omi Jordani pada si ipò rẹ̀, o si ṣàn bò gbogbo bèbe rẹ̀, gẹgẹ bi ti iṣaju.

19. Awọn enia si ti inu Jordani gòke ni ijọ́ kẹwa oṣù kini, nwọn si dó ni Gilgali, ni ìha ìla-õrùn Jeriko.

Ka pipe ipin Joṣ 4