Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 22:7-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Njẹ fun àbọ ẹ̀ya Manasse ni Mose ti fi ilẹ-iní wọn fun ni Baṣani: ṣugbọn fun àbọ ẹ̀ya ti o kù ni Joṣua fi ilẹ-iní fun pẹlu awọn arakunrin wọn ni ìha ihin Jordani ni ìwọ-õrùn. Nigbati Joṣua si rán wọn pada lọ sinu agọ́ wọn, o sure fun wọn pẹlu,

8. O si wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ pẹlu ọrọ̀ pipọ̀ si agọ́ nyin, ati pẹlu ohunọ̀sin pipọ̀, pẹlu fadakà, ati pẹlu wurà, ati pẹlu idẹ ati pẹlu irin, ati pẹlu aṣọ pipọ̀pipọ: ẹ bá awọn arakunrin nyin pín ikogun awọn ọtá nyin.

9. Awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse si pada, nwọn si lọ kuro lọdọ awọn ọmọ Israeli lati Ṣilo, ti mbẹ ni ilẹ Kenaani, lati lọ si ilẹ Gileadi, si ilẹ iní wọn, eyiti nwọn ti gbà, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA lati ọwọ́ Mose wá.

10. Nigbati nwọn si dé eti Jordani, ti mbẹ ni ilẹ Kenaani, awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse mọ pẹpẹ kan lẹba Jordani, pẹpẹ ti o tobi lati wò.

11. Awọn ọmọ Israeli si gbọ́ pe, Kiyesi i, awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse mọ pẹpẹ kan dojukọ ilẹ Kenaani, lẹba Jordani ni ìha keji awọn ọmọ Israeli.

12. Nigbati awọn ọmọ Israeli gbọ́ ọ, gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli kó ara wọn jọ ni Ṣilo, lati gòke lọ ibá wọn jagun.

13. Awọn ọmọ Israeli si rán Finehasi ọmọ Eleasari alufa si awọn ọmọ Reubeni, ati si awọn ọmọ Gadi, ati si àbọ ẹ̀ya Manasse ni ilẹ Gileadi;

14. Ati awọn olori mẹwa pẹlu rẹ̀, olori ile baba kọkan fun gbogbo ẹ̀ya Israeli; olukuluku si ni olori ile baba wọn ninu ẹgbẹgbẹrun Israeli.

15. Nwọn si dé ọdọ awọn ọmọ Reubeni, ati ọdọ awọn ọmọ Gadi, ati ọdọ àbọ ẹ̀ya Manasse, ni ilẹ Gileadi, nwọn si bá wọn sọ̀rọ pe,

16. Bayi ni gbogbo ijọ OLUWA wi, Ẹ̀ṣẹ kili eyiti ẹnyin da si Ọlọrun Israeli, lati pada li oni kuro lẹhin OLUWA, li eyiti ẹnyin mọ pẹpẹ kan fun ara nyin, ki ẹnyin ki o le ṣọ̀tẹ si OLUWA li oni?

17. Ẹ̀ṣẹ ti Peori kò to fun wa kọ́, ti a kò ti iwẹ̀mọ́ ninu rẹ̀ titi di oni, bi o tilẹ ṣe pe ajakalẹ-àrun wà ninu ijọ OLUWA,

18. Ti ẹnyin fi pada kuro lẹhin OLUWA li oni? Yio si ṣe, bi ẹnyin ti ṣọ̀tẹ si OLUWA li oni, li ọla, on o binu si gbogbo ijọ Israeli.

19. Njẹ bi o ba ṣepe ilẹ iní nyin kò ba mọ́, ẹ rekọja si ilẹ iní OLUWA, nibiti agọ́ OLUWA ngbé, ki ẹ si gbà ilẹ-iní lãrin wa: ṣugbọn ẹnyin má ṣe ṣọ̀tẹ si OLUWA, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ si wa, ni mimọ pẹpẹ miran fun ara nyin lẹhin pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa.

20. Ṣe bẹ̃ni Akani ọmọ Sera da ẹ̀ṣẹ niti ohun ìyasọtọ, ti ibinu si dé sori gbogbo ijọ Israeli? ọkunrin na kò nikan ṣegbé ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

Ka pipe ipin Joṣ 22