Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 2:14-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Awọn ọkunrin na da a lohùn pe, Ẹmi wa ni yio dipò ti nyin, bi ẹnyin kò ba fi ọ̀ran wa yi hàn; yio si ṣe, nigbati OLUWA ba fun wa ni ilẹ na, awa o ṣe ore ati otitọ fun ọ.

15. Nigbana li o fi okùn sọ̀ wọn kalẹ li oju-ferese: nitoriti ile rẹ̀ wà lara odi ilu, on a si ma gbé ori odi na.

16. O si wi fun wọn pe, Ẹ bọ sori òke, ki awọn alepa ki o má ba le nyin bá; ki ẹnyin si fara nyin pamọ́ nibẹ̀ ni ijọ́ mẹta, titi awọn alepa yio fi pada: lẹhin na ẹ ma ba ọ̀na ti nyin lọ.

17. Awọn ọkunrin na wi fun u pe, Ara wa o dá niti ibura rẹ yi, ti iwọ mu wa bú.

18. Kiyesi i, nigbati awa ba dé inu ilẹ na, iwọ o so okùn owú ododó yi si oju-ferese ti iwọ fi sọ̀ wa kalẹ: iwọ o si mú baba rẹ, ati iya rẹ, ati awọn arakunrin rẹ, ati gbogbo ara ile baba rẹ, wá ile sọdọ rẹ.

19. Yio si ṣe, ẹnikẹni ti o ba jade lati inu ilẹkun ile rẹ lọ si ode, ẹ̀jẹ rẹ̀ yio wà li ori ara rẹ̀, awa o si wà li aijẹbi: ati ẹnikẹni ti o ba wà pẹlu rẹ ni ile, ẹ̀jẹ rẹ̀ yio wà li ori wa, bi ẹnikẹni ba fọwọkàn a.

20. Bi o ba si sọ ọ̀ran wa yi, nigbana ni ara wa o dá niti ibura rẹ ti iwọ mu wa bú yi.

21. O si wipe, Gẹgẹ bi ọ̀rọ nyin, bẹ̃ni ki o ri. O si rán wọn lọ, nwọn si lọ: o si so okùn ododó na si oju-ferese.

22. Nwọn si lọ, nwọn si dé ori òke, nwọn si gbé ibẹ̀ ni ijọ́ mẹta, titi awọn alepa fi pada: awọn alepa wá wọn ni gbogbo ọ̀na, ṣugbọn nwọn kò ri wọn.

23. Bẹ̃li awọn ọkunrin meji na pada, nwọn si sọkalẹ lori òke, nwọn si kọja, nwọn si tọ̀ Joṣua ọmọ Nuni wá; nwọn si sọ ohun gbogbo ti o bá wọn fun u.

24. Nwọn si wi fun Joṣua pe, Nitõtọ li OLUWA ti fi gbogbo ilẹ na lé wa lọwọ; nitoripe ọkàn gbogbo awọn ara ilẹ yi di omi nitori wa.

Ka pipe ipin Joṣ 2